Peter yii ma daju o, laarin ọjọ meje ti wọn gba a siṣẹ lo pa ọga ẹ l’Ekoo

Inu ibanujẹ lawọn mọlẹbi ati aladuugbo mama kan ti ko ti i sẹni to mọ orukọ ẹ, to n gbe lagbegbe Gbagada, nipinlẹ Eko, wa bayii, pẹlu bi ọmọọdọ ti wọn ṣẹṣẹ gba fun un ṣe gbẹmi ẹ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Vanguard ṣe sọ, ko sẹni to le sọ pato igba ti ọmọ-ọdọ ti wọn n pe ni Peter ọhun ṣiṣẹ ibi yii, nitori oku mama ti n wu ki wọn too mọ.

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni ọkan ninu awọn ọmọ mama naa to jẹ ọkunrin wa a wa sile ti wọn n da gbe ni 29, Kiniun-Ifa street, Sawmill, Gbagada, nipinlẹ Eko, amọ to jẹ ẹnu sitẹnpu inu ile lo ti ba oku mama, pẹlu apola igi lẹgbẹẹ rẹ.

Yatọ si ṣọọbu mẹta ti wọn yọ siwaju ile naa, oloogbe nikan ni wọn lo n da gbenu ile ọhun lai si ayalegbe kankan to n ba a gbe.

Owuyẹ kan laduugbo naa ṣalaye pe, “Ọmọ mama yẹn to jẹ ọkunrin lo wa, bo ṣe n wọnu agbala ile naa, ọdọ mama lo gba lọ taara, amọ ori sitẹnpu ti wọn n gun lọ soke lo ti ri oku mama pẹlu apa ẹjẹ.

“Igi nla kan wa lẹgbẹẹ wọn, eyi ti wọn fura si pe o ṣee ṣe ko jẹ ọkan lara nnkan ti wọn fi pa mama agbalagba náà niyi. Ni gbogbo igba ta a n sọ yii, oku yẹn ti n wu, leyii to tumọ si pe o ti to ọjọ meloo kan ti wọn pa mama, ṣugbọn ti ẹnikẹni ko mọ”.

Ko ti i ju ọsẹ kan lọ ti ọmọọdọ ti wọn fura si, to si ti na papa bora ọhun, bẹrẹ iṣẹ lọdọ mama.

Ọkan lara awọn mọlẹbi wọn ni wọn lo ba wọn wa ọmọ yii. Mọlẹbi to mu un wa yii naa ni wọn fi panpẹ ofin gbe, niwọn igba ti wọn ko ti ri ẹni to fun wọn lọmọọdọ naa.

Awọn ọlọpaa teṣan Ifakọ, to sun mọ tosi ibudo iṣẹlẹ naa ti yọju sibẹ lati palẹ oku mama mọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Alukooro ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ṣalaye pe ọwọ ti tẹ ọmọ-ọdọ naa, wọn si ti taari rẹ lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti wọn ti n wadii iwa ọdaran, SCID, to wa ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko.

Leave a Reply