Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Inu ibanujẹ ati ọfọ ni mọlẹbi Lukman to jẹ dẹrẹba, to n fọkọ na ọgba Fasiti Ilọrin, niluu Ilọrin, si Tankẹ, wa bayii. Ohun iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo awọn to wa ninu mọto ọhun pe ṣe ni dẹrẹba naa sadeede ku lojiji, lasiko to n gbe awọn akẹkọọ lati agbegbe Tankẹ, lọ si inu ọgba ileewe ọhun.
ALAROYE gbọ pe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni iṣẹlẹ buruku naa ṣẹ, niṣe lo deede dori kodo, ti ko si le dari ọkọ naa mọ. Ki awọn to wa ninu ọkọ ọhun too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọkunrin naa ti ku patapata.
Ọkan lara awọn ero to gbe, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe oun loun da ọkọ naa duro. Nigba to n ṣọrọ nipa iṣẹlẹ naa, o ni lati agbegbe Tankẹ Sanrab, ni oloogbe ti gbe awọn, to si n gbe awọn lọ sinu ọgba ileewe, ati pe iwaju ni oun jokoo si. O ni sadeede ni oun ri i pe dẹrẹba ti mori lọọlẹ lori ere, eyi to mu ki ọkọ maa wọ inu igbo lọ, ṣugbọn oun sare tẹ bireeki ọkọ naa, to si duro, bo tilẹ jẹ pe aya awọn ti ja nigba tawọn ri i pe ọkọ ti ya kuro loju ọna. O ni, “Ọkọ n gbe wa lati Ṣanrab lọ Unilọrin, iwaju ni mo jokoo si, mi o woke, nitori pe mo n ka kurani lọwọ lori foonu mi.
“Ẹni to wa lẹgbẹẹ mi lo pe akiyesi mi, to si n pariwo, ‘baba-baba’ lera wọn, mo sare fẹṣẹ tẹ bireeki, ọkọ si duro. Wọn sare gbe dẹrẹba naa lọ si kiliniiki ileewe, nibi to ti dagbere faye, gbogbo ohun to ṣẹlẹ ko ju ọgbọn iṣẹju lọ.
Ọkan lara awọn dẹrẹba ẹlẹgbẹ rẹ, Sulyman Malik, ni l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọn kẹẹẹdogun, oṣu yii, lọkunrin to doloogbe yii ṣi n ki oun nipa ijamba ọkọ toun ni laipẹ. O ni ọkunrin dẹrẹba ọhun ko ti i ju ẹni ọgbọn ọdun lọ.
Nigba to n ṣọrọ, adari ẹka to n gbe iroyin jade ni Fasiti Ilọrin, Ọgbẹni Kunle Akọgun, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to gba omi loju ẹni.
Wọn ti sinku Lukman nilana ẹṣin Musulumi.