Kazeem Aderohunmu
Ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin ni ajalu nla kan de ba gbajumọ aṣaaju awọn olorin waka nilẹ yii, Alhaja Salawa Abẹni. Akọbi ẹ lọkunrin, Idris Ọlanrewaju Adefọlajuwọn Akanji Adepọju, lo ku lojiji. Ọsẹ to kọja, iyẹn ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọdun 2000 yii, gan-an lo pe ogun ọdun geere ti ọmọ oṣere naa ku.
Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni lọdun naa lọhun-un, ṣugbọn bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn eeyan le ti gbagbe pe iṣẹlẹ naa waye, sibẹ, Salawa Abẹni ko gbagbe, oun gan-an naa lo gba ori instagiraamu rẹ lọ, to si kọ ọ sibẹ bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye, ati iru idaamu to ba a nigba ti iku pa Akanni, ọmọkunrin to bi fun Adepọju loju de lọdun naa lọhun-un.
Bi Salawa Abẹni ṣe kọ ọrọ ọhun ree: ‘‘Hmmm!! Loni-in ọjọ keji, oṣu kẹwaa yii, gan-an lo pe ogun ọdun ti o ti fi mi silẹ lọ. Akọbi mi lọkunrin, Idris Olanrewaju Adefọlajuwọn Akanji Adepọju. Bii ana lo ṣe ri o, ṣugbọn iṣẹlẹ ọhun ti pe ogun ọdun geere loni-in. Idaamu nla ni iku ojiji to pa ọ yii ko ba mi. Lanre, bẹẹ ni iku rẹ fẹẹ sọ aye mi di bami-in paapaa, koda, o ko ifasẹyin ba iṣẹ orin ti mo gbe lọwọ debii pe ṣe lawọn eeyan n beere pe ṣe mi o kọrin mọ ni?
“Ju gbogbo ẹ lọ, ki a ṣaa maa dupẹ lọwọ Ọlọrun to fun mi lokun ati agbara lati ṣi wa laye loni-in.
“Mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn duro ti mi pata latigba yẹn titi di asiko yii. Mo waa n fi asiko yii gba a laduura fun gbogbo abiyamọ aye pe ẹ o ni i ri iku ọmọ lagbara Ọlọrun. Ẹyin ti iru ẹ si ti ṣẹlẹ si, idunnu to n bori ibanujẹ ni Ọlọrun aa ṣe fun gbogbo wa, amin.
“Ọdun yii gan-an ni iwọ naa o ba pe ẹni ọdun mẹtadinlogoji, ọkan mi ṣafẹẹri rẹ, bẹẹ lawọn aburo rẹ paapaa naa n ṣafẹẹri rẹ gidigidi. Gbogbo wa pata la fẹ ọ, ṣugbọn Ọlọrun Allah lo fẹ ọ ju, titi ta oo tun fi pade, ṣe ni ki o maa sinmi laya Oluwa rẹ, emi iya rẹ ni o, Alhaja Salawa Abẹni.”
Bo ti ṣe kọ ọrọ ọhun ree, bẹẹ lawọn ẹbi, ara, ojulumọ n fi ọrọ tutu ranṣe si i, ti wọn si n ba a kẹdun gidigidi pẹlu adura pe Ọlọrun yoo tubọ rọ ọ loju, awọn yooku to wa lọwọ rẹ yoo si ba a kalẹ.