Oṣere tiata yii figbe bọnu: Ẹ gba mi o, wọn ti wọ gbogbo owo inu akaunti mi lọ!

Faith Adebọla

Gbajumọ oṣere-binrin onitiata ilẹ wa, Shan George, ti kegbajare sawọn agbofinro ati gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn ma wo oun niran, ki wọn gba oun, o ni gbogbo miliọnu mẹta aabọ Naira to wa ninu akaunti banki oun ni wọn ti wọ jade lojiji, korofo ni akaunti oun si wa bayii.

Shan George, apọnbeporẹ to saaba n maa n kopa ninu awọn fiimu ede oyinbo, lo figbe bọnu bẹẹ lori ẹrọ ayelujara lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ta a wa yii.

O ni lojiji loun kan ri alaati to wọ ori foonu oun, ẹnikan to pe orukọ rẹ ni Cecilia Chagoziem Okoro, ni atẹjiṣẹ naa gbe jade pe o wọ owo ọhun, afi b’oun ṣe ni koun yẹ ẹrọ aapu banki Zenith to wa lori foonu oun wo, lo ba di gbọ-in, aapu naa ko ṣiṣẹ, boya wọn ti i pa ni o, boya nẹtiwọọku si ni, oun o ṣaa ribi wọle, nigba toun si tun wa ọgbọn mi-in da lati mọ ohun to n ṣẹlẹ loun ri i pe ilẹ ti mọ, miliọnu mẹta ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira (N3.6m) ni wọn ti gbọn jade. Inu akaunti OPAY kan lowo naa wọ, oun ko si mọ ẹnikẹni to n jẹ Cecilia nibikibi, bẹẹ loun ko laadehun kan tabi da nnkan to jẹ mọ okoowo pọ pẹlu ẹnikẹni.

Pẹlu ẹdun ọkan ni obinrin yii fi yaworan awọn atẹjiṣẹ ti wọn fi gbọn owo rẹ lọ ọhun sori ikanni ayelujara rẹ, o si kọ ọrọ sabẹ fọto naa, o ni:

“Mo nilo iranlọwọ, tori mo ti n ku lọ o. Niṣe lẹni yii palẹmọ gbogbo owo to wa ninu akaunti mi, o gba a mọ fefe ni o.

“Ẹ jọọ, ẹyin eeyan mi, mo bẹ gbogbo yin, ẹ jọọ, ẹyin alaṣẹ Zenith Bank, OPAY, mo bẹbẹ, ẹ ran mi lọwọ, Ọlọrun ni mo fi bẹ yin.

“Mi o ni kọbọ nibikibi mọ, ki ni mo fẹẹ jẹ bayii? Mi o le maa tọrọ jẹ, mo bẹ yin, ẹ ran mi lọwọ. EFCC, ẹyin ọlọpaa Naijiria, ẹ jọwọ, mi o mọ awọn alaṣẹ ti mo le kigbe lọọ ba, ẹyin oṣiṣẹ Zenith Bank, mo n bẹ ẹyin eeyan yii ni o. Ẹ ba mi da owo mi pada o, Mi o tiẹ le wọ ori app mi mọ bayii, mo ti ku o.

“Oni ọjọ kẹta yii lo ṣẹlẹ, ko ti i ju wakati kan si meji lọ sasiko ti mo n ṣe fidio yii o, ẹ jọọ, ẹ ba mi wa nnkan ṣe, mo bẹbẹ ni o.”

Bẹẹ ni Shan George parọwa taaanu-taaanu o.

Leave a Reply