Iyawo mi purọ mọ mi ni, mi o ba ọmọ mi laṣepọ- Taiwo

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Rahman Oshodi, tile- ẹjọ akanṣe kan to n ri si lilo ọmọde niilokulo nipinlẹ Eko, ‘Special Offences Court’, to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, ni wọn foju baale ile kan, Ọgbẹni Taiwo, ba. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fipa ba ọmọ rẹ, Ẹniọla Taiwo, ọmọọdun mẹrin sun lọdun 2020. Latigba naa lo ti wa lahaamọ ọgba ẹwọn Kirikiri, niluu Eko, ki wọn too gbe wa si kootu lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Nigba ti olujẹjọ naa n ṣalaye taanu taanu niwaju adajọ, o ni ọmọ mẹta niyawo oun bi fun oun, ṣugbọn oun ko mọ idi ti obinrin naa ṣe maa n parọ banta-banta mọ oun pe oun fipa b’ọmọ oun sun.

O ni, ‘Oluwa mi, iṣẹ kapẹnta ni mo n ṣe lagbegbe Badoore, niluu Ajah, nipinlẹ Eko. Iyawo mi lo saaba maa n wa pẹlu awọn ọmọ mi nigba gbogbo, ọkunrin meji, obinrin kan ni mo bi. Lọjọ kan lọdun 2020, niyawo mi sọ pe kokoro mu ọmọ mi Ẹniọla labẹ, mo fun un lowo pe ko mu ọmọ naa lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe wa, nigba to de lo ni dokita ṣalaye foun lọsibitu pe ẹni kan ti fipa ja ibale ọmọ naa.

‘‘Inu mi ko dun rara, mo mọ daju pe mi o ki i si nile nigba gbogbo lati mojuto awọn ọmọ naa, ileewe tawọn ọmọ mi n lọ naa niyawo mi ti n ṣisẹ, bi wọn ba kuro nibẹ, ṣọọṣi ni wọn maa n dari si, mi o mọ bọrọ naa ṣe jẹ, ṣugbọn ohun to jẹ kọrọ naa dun mi gidi ni pe ibatan mi kan, Ọgbẹni Adeọla, ti i ṣe ẹgbọn mi wa pẹlu iyawo mi lọjọ ti wọn maa mu ọmọ naa lọ sileewosan alaadani kan lẹẹkeji lai jẹ ki n mọ si i. Wọn ni esi kan naa ni wọn gba bọ lati ileewosan naa, wọn si ni ọmọ mi darukọ mi pe emi ni mo fika ro oun nidii lati ja ibalẹ rẹ.

‘‘Mi o ki i ṣe oniranu eeyan o, mi o raaye gbele, o ṣe waa jẹ pe ọmọ mi ni ma a waa fipa ja ibale rẹ lọsan-an gangan.

Nigba ti agbefọba , Ọgbẹni Boye, n beere ọrọ lọwọ olujẹjọ, o ni bawo lo ṣe jẹ pe ninu gbogbo awọn t’ọmọ naa mọ daadaa, orukọ olujẹjọ yii nikan lo da nibi mẹta ọtọọtọ. Akọkọ ni ileewosan ijọba kan to wa lagbegbe Badoore, niluu Ajah, ibi keji ni ileewosan alaadani kan ti wọn ti lọọ ṣayẹwo fun un, nigba ti ibi kẹta jẹ ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Badoore yii kan naa, ti ọrọ ọmọ naa ko si tase rara fun igba mẹtẹẹta naa.

Ati pe bi ki i baa ṣe pe olujẹjọ ti mọ iwa laabi to hu s’ọmọ naa ni, o yẹ ko wa pẹlu iyawo rẹ, o kere tan, fun igba kan laarin akoko ti wọn mu ọmọ naa lọ sileewosan lẹẹmeji ọtọọtọ. Ati pe nigba ti olujẹjọ faake kọri ti ko yọju sawọn ọlọpaa agbegbe naa ti wọn lọọ fọrọ rẹ to leti lawọn yẹn ṣe da a bii ọgbọn, ti wọn si lọọ mu un nibi to wa, ko too di pe wọn foju rẹ bale-ẹjọ.

Ṣa o, ọrọ kan ṣoṣo ti olujẹjọ n sọ ni pe oun kọ loun huwa ti ko bofin mu ọhun si ọmọ oun to si ni ki Ọlọrun Ọba gbe oun nija lori ọrọ naa.

Lẹyin awijare olupẹjọ ati olujẹjọ, adajọ sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii. Bakan naa lo rọ olupẹjọ pe ko ri i daju pe iyawo ati ọmọ olujẹjọ ti wọn le sọrọ ta ko olujẹjọ wa nile-ẹjọ lọjọ naa, k’oun baa le beere awọn ọrọ lẹnu wọn.

Leave a Reply