O ma ṣe o, awọn meji dagbere faye lẹyin ti wọn mu agbo jẹdi tan n’Ìpè Akoko 

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ajalu nla lo ṣẹlẹ niluu Ìpè Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, lopin ọsẹ ta a lo tan yii pẹlu bi awọn meji ṣe ku lojiji lẹyin ti wọn mu agbo tan, ti alufaa to gbadura fun wọn naa si tun binu wọ ile rẹ lọọ p’okunso ni kete to gbọ iku awọn eeyan ọhun.

ALAROYE gbọ pe lasiko ayẹyẹ ọdun kan ti wọn n pe ni Ibogbe, eyi ti wọn ṣe lopin ọsẹ to kọja yii lawọn eeyan kan ko ara wọn jọ lasiko ti ayẹyẹ ọdun naa n lọ lọwọ, ti wọn si jọ n mu agbo ibilẹ kan ti ẹnikan gbe fun wọn.

Bi wọn ṣe n mu agbo yii tan lọrọ bẹyin yọ, ti nnkan si daru mọ awọn to mu agbo naa lọwọ patapata.

A gbọ pe loju-ẹsẹ ni meji ti ku lara wọn, iyẹn ẹni to gbe agbo fun wọn mu ati alejo kan ti wọn lo tori ọdun ibilẹ naa wale lati ilu Abuja to fi ṣe ibugbe. Ẹni kẹta wọn ni wọn lo ṣi wa ni ẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun ni ọsibitu ijọba to wa niluu Ikarẹ Akoko, nibi ti wọn ti n tọju rẹ lọwọ.

Iroyin ti alufaa ijọ Angilika kan ta a f’orukọ bo laṣiiri gbọ ree to fi wọnu Ile rẹ lọ lati lọọ p’okunso.

Wọn ni alufaa to ti ṣiṣẹ Oluwa fẹyinti ọhun sọ ninu iwe to funra rẹ kọ silẹ ko too gba ẹmi ara rẹ pe ṣe loun mọ-ọn-mọ pa ara oun pẹlu bi Ọlọrun ṣe kọ lati gbọ adura ti oun gba fun awọn to ku ọhun saaju iṣẹlẹ naa.

Wọn ni alufaa ọhun ṣalaye sinu iwe akọsilẹ rẹ pe oun ti kọkọ gbadura fawọn eeyan ọhun ṣaaju, ti inu oun ko si dun si bi iru iṣẹlẹ buruku bẹẹ ṣe tun le sẹlẹ si wọn lẹyin gbogbo adura ti oun ti gba fun wọn.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, sibẹ, wọn ni oku alufaa naa ṣi wa lori ìṣo ninu ile rẹ ni gbogbo asiko ti awa fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.

ALAROYE gbọ pe loootọ l’awọn ọlọpaa ti ṣe abẹwo sibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ibẹru ko le jẹ ki wọn fọwọ kan oku ojisẹ Ọlọrun naa nibi to pokunso si pẹlu bi wọn ṣe lawọn eeyan rẹ ko ti i ṣe etutu to yẹ ki wọn too le ja a silẹ lori iso to wa.

Leave a Reply