Awọn aṣofin Eko buwọ lu atunṣe eto iṣuna

Faith Adebọla, Eko

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti ṣagbeyẹwo aba eto iṣuna ipinlẹ naa lakọtun, wọn si ti fọwọ si owo ti iye rẹ le ni okoolelẹẹẹdẹgbẹrun biliọnu naira (₦920,468,589,337) fun iṣakoso ti Gomina Babajide Sanwo-Olu n tukọ rẹ.

Nibi ijiroro wọn to waye ni gbọngan apero ile igbimọ aṣofin ọhun lọjọ Aje, Mọnde, ana, ni wọn ti fẹnuko ti wọn si faṣẹ si aba eto iṣuna ọhun.

Ṣaaju lawọn aṣofin ti pin iṣẹ naa fun awọn igbimọ alabẹ-ṣekele rẹ lori eto ọrọ-aje ati iṣuna (Economic Planning and Budget) ati ti inawo (Finance) lati kọkọ lọọ forikori latari bi Gomina ṣe da eyi ti wọn ti kọkọ fọwọ si pada.

Tẹ o ba gbagbe, inu oṣu kejila, ọdun to kọja, lawọn aṣofin naa kọkọ fọwọ si aba eto iṣuna towo rẹ le ni tiriliọnu kan naira fun ọdun ta a wa yii, ti Gomina Sanwo-Olu si ti buwọ lu u.

Lẹyin eyi ni laasigbo ajakalẹ arun Koronafairọọsi yọ kẹlẹ wọle loṣu keji, o si ṣe bẹẹ burẹkẹ si i nipinlẹ Eko, eyi to ṣe ipalara fun karakata, eto ọrọ-aje ati iṣẹ ọba nipinlẹ naa latari bi ofin konilegbele ṣe gbode.

Eyi lo mu ki Gomina Sanwo-Olu woye pe atunṣe ni lati ba eto iṣuna naa lati le mu un ba igba mu.

Alaga igbimọ alabẹ-ṣekele to po eto iṣuna tuntun yii pọ, Ọnarebu Gbọlahan Yishawu lati agbegbe Eti-Ọsa Keji sọ pe awọn iwadii gboogi to to ọgọfa lawọn ṣe lakọtun, to si mu kawọn ṣatunṣe si abala bii ọgọfa ninu aba eto iṣuna tuntun naa.

Ninu ọrọ ikadii rẹ, Abẹnugan ile aṣofin ọhun, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, sọ pe aba eto iṣuna tuntun yii ti wọgile nnkan bii ida mọkanlelogun (21%) kuro ninu eyi tawọn ti kọkọ ṣe tẹlẹ, ṣugbọn ireti wa pe aba tuntun yii yoo ṣe daadaa nitori awọn gbe e kari bi eto ọrọ-aje ati iṣẹ ijọba ṣe ri lasiko yii.

O waa paṣẹ pe ki akọwe ile aṣofin naa, Ọnarebu Azeez Sanni, ṣeto ẹda abadofin naa lai jafara, ko si fi i ṣọwọ si ọfiisi Gomina Sanwo-Olu fun ibuwọlu rẹ.

 

Leave a Reply