Kayeefi nla! Niluu Ifọn, ara san pa maaluu meje

Fun igba akọkọ niluu Ifọn Ọṣun, maaluu meje ni ara nla to san lasiko ojo nla kan to rọ loru mọjumọ oni pa.

Abule kan ti wọn n pe ni Elepo Village, nijọba ibilẹ Orolu niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Ibi ti awọn Fulani darandaran ko awọn maaluu ọhun pamọ si lẹyin ti wọn fi wọn jẹko tan ni ara ti san pa wọn.

Nigba ti awọn oniroyin pe Olufọn tiluu Ifọn Orolu, Ọba Almaroof Magbagbeọla, lori foonu lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, kabiyesi sọ pe awọn yoo pe pada.

Leave a Reply