O fẹẹ jọ pe lojoojumọ ni wahala to wa ninu igbeyawo minisita feto irinna ọkọ ofurufu tẹlẹ, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, n fojoojumọ le si i pẹlu fidio kan to gba igboro kan bayii.
Precious Chikwendu lorukọ iyawo ẹ yii, o si ti to ọjọ mẹta bayii ti awuyewuye ti gbalu pe igbeyawo naa ti fori ṣanpọn, ṣugbọn ti wọn kọkọ n dọwo bo o, ki aṣiri bọrọ ọhun ṣe jẹ gan-an too tu sita patapata.
Fidio kan ti ko ju iṣẹju mọkanlelogun lọ nileeṣẹ iwe iroyin kan gbe jade, nibi ti ariyanjiyan kan ti n ṣẹlẹ laaarin Fẹmi ati iyawo ẹ yii, oju tawọn eeyan si fi n wo iṣẹlẹ ọhun ni pe ṣe ni Fẹmi n fiya jẹ obinrin naa.
Fẹmi Fani-Kayọde naa ti sọrọ, ori ẹrọ abẹyẹfo ẹ twitter, lo gba lọ. Alaye to si ṣe ni pe ọdọkọ niyawo oun, ori bẹẹdi oun gan-an, nibi tawọn ti jọ n ṣe lọkọ-laya lo gbe ọkunrin kan wa, ti wọn jọ ka mọ ara wọn daadaa nibẹ.
O ni lẹyin ọjọ meloo kan ti iṣẹlẹ ọhun waye, ti iyawo oun bẹrẹ si i ba gbogbo ile ja, to tun n kanra mọ awọn ọmọ, ti awọn oṣiṣe gan-an ko mọ ohunkohun un ṣe mọ nile loun pe e wi pe ko jẹ ki ogun o sinmi.
Minisita tẹlẹ yii sọ pe niṣe niyawo oun fa foonu ẹ yọ, to fẹẹ maa fi kamẹra rẹ ya oun bi oun ṣe n ba a sọrọ, ti ariyanjiyan si ṣe bẹẹ waye, eyi ti wọn n gbe kiri bayii, bẹẹ ki i ṣe pe oun lu obinrin naa tabi fiya kankan jẹ ẹ.
Ọmọ mẹrin lawọn tọkọ-taya yii bi funra wọn, ninu eyi ti awọn ibeta wa ninu ẹ paapaa.
Ki ole danu
Some wowan are just useless
Kin wonlo she dna test fun awon omo Tobi fun yin