Ọwọ sifu difẹnsi tẹ ọkọ ti awọn ọdaran yii fi ji ewurẹ rẹpẹtẹ ko l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti 

Ajọ sifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Ekiti, ti kede pe ọwọ wọn ti tẹ ọkọ ayọkẹlẹ Toyota  Camry kan ti wọn fi n ji ewurẹ ko nipinlẹ Ekiti.

Alukoro ajọ naa nipinlẹ yii, Ọgbẹni Tolulope Afọlabi, ṣalaye pe awọn ọmọ ogun ajọ naa ti wọn n gbogun ti iwa agbesunmọmi, (Counter terrorism) ni wọn ṣeto kan ti wọn fi n fimu finlẹ ni agbegbe Adebayo, ni Ado-Ekiti. Lasiko naa ni wọn da ọkọ kan ti ewurẹ to to bii mẹrinla wa ninu rẹ duro. lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii. Wọn da ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry naa duro, wọn si ri i pe ewurẹ ti wọn ji ko lo wa ninu ọkọ naa.

Adọlabi sọ pe ọkọ naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ, LSR 84 AY to jẹ alawọ eeru, lo n bọ lati ọna to lọ si Yunifásítì ipinlẹ Ekiti, to si n wọ inu igboro Ado-Ekiti lọ.

O fi kun un pe ni kete ti dẹrẹba ọkọ naa ati awọn meji to wa ninu rẹ ti foju gan-an-ni awọn sifu difẹnsi naa ni wọn ti bẹ silẹ ninu ọkọ naa, ti wọn si fere ge e.

O sọ pe awọn ewure naa to to bii mẹrinla ni wọn fi nnkan di lẹnu debi ti o ṣoro fun wọn lati kigbe.

Alukoro sọ pe awọn ti lọọ ṣe ikede fun awọn araalu ti ewurẹ wọn ba sọnu lagbegbe naa tabi ni awọn ilu miiran, ki wọn kan si olu ileeṣẹ ajọ naa to wa ni oju ọna Ado-Ekiti si Afao.

O fi kun un pe awọn ti n san gbogbo ọna lati ri i pe ọwọ tẹ awọn ọdaran naa lati le foju kata ina ofin. O tun rọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti pe ki ẹnikẹni to ba mọ ohunkohun nipa awọn afurasi yii gbiyanju lati waa sọ fun ajọ naa.

Leave a Reply