Bi eto idibo gomina nipinlẹ Ondo ṣe n kanlẹkun gbọngbọn, eyi ti yoo waye lopin ọsẹ yii, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti pariwo sita pe ti ojooro tabi madaru kan ba fi le waye lasiko idibo naa, awọn ko ni i gba rara.
Ọgbẹni Kọla Ọlọgbọndiyan to jẹ alaga fun eto ipolongo igbimọ to n polongo ibo fun Eyitayọ Jẹgẹdẹ, oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu wọn lo sọrọ yii niluu Abuja laipẹ.
O ni ṣaaju asiko yii lọkunrin kan ti wọn n pe ni Isaac Kẹkẹmẹkẹ, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ti n leri kiri pe agbara ijọba apapọ lawọn maa lo, ati pe gbogbo ohun to ba gba pata lawọn yoo fun un lati ri i pe Rotimi Akeredolu tun pada sipo gomina lẹẹkan si i.
Ọlọgbọndiyan ti waa rọ ijọba Buhari lati ri i daju pe awọn eeyan ẹ ko ṣi i lọna, ko jẹ ki eto idibo Ondo lọ wọọrọ, ko ma da si i gẹgẹ bo ti ṣe lasiko ibo ipinlẹ Edo, ti gbogbo aye si ri i pe ibo to yaranti ni.
O ni ti Buhari ba le ṣe eleyii lẹẹkan si i, yoo fi i han gẹgẹ bii ẹni to sa ipa rere lasiko tiẹ lori bi eto idibo gidi ṣe waye ni Naijiria.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Rotimi Makinde, ẹni ti i ṣe alaga fun eto ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ondo naa ti sọ pe erongba rere ti awọn eniyan ni fun ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa yoo wa si imuṣẹ, bo tilẹ jẹ pe gbogbo ọna lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC n wa lati ṣeru ninu ibo ọhun.
Ṣa o, Alukoro feto ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu APC, Alex Kalejaye, naa ti sọrọ, o ni ẹgbẹ oṣelu PDP gan-an lo fẹẹ da wahala silẹ nipinlẹ naa, nitori awọn ni wọn n ko janduku kiri, ti wọn si n ṣe araalu leṣe.
O ni ohun ti ẹgbẹ naa fi ṣe akọmọna wọn, “Eyitayọ Jẹgẹdẹ ko gbọdọ fidi-rẹmi”maa n jẹ ki ori awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP maa wu, paapaa awọn to jẹ ọdọ laarin wọn, ti wọn a maa ba nnkan jẹ, ti wọn si n ṣe araalu leṣe kiri, paapaa awọn ti wọn jẹ ololufẹẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
O waa fi kun un pe ohun to da oun loju ju lọ ni aṣeyori ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina to maa waye yii, ki awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lọọ jokoo jẹẹ.
Enter your comment here…olorun awo inu won lo