Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Pẹlu bawọn eeyan orileede yii ṣe n figba gbogbo kigbe tantan pe ilu le, sibẹ, Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Alhaji Abdullah Ganduje, ti ni akọ iṣẹ ati ojulowo iṣẹ ni olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, n ṣe lọwọ lati gbe iṣakoso ijọba rẹ de ebute ayọ. O ni laipẹ, laijina, awọn araalu maa bẹrẹ si i jẹ igbadun iṣẹ idagbasoke gbogbo ti Aarẹ Tinubu n ṣe lati igba to ti dori aleefa.
Ilu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ni Alhaji Ganduje ti sọrọ ọhun di mimọ lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ igbimọ kan to maa ri si eto ipolongo ibo fun ondije dupo gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Lucky Ayedatiwa, eyi to maa waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’Aarẹ Tinubu ti ṣe awọn eto oniruuru to maa too bẹrẹ si i so eeso rere laipẹ fawọn eeyan orileede yii. Nnkan maa too bẹrẹ si i dẹrun, awọn ofin to ṣe maa jẹ ki orileede yii ni ilọsiwaju si i ni. Akọ iṣẹ gidi lo n ṣe latigba to ti depo aṣẹ ijọba orileede yii, mo gboriyin fun un nipa awọn iṣẹ akin kọọkan to n ṣe lọwọ.