Ẹgbẹ awọn to ṣe idasilẹ ileepo bẹntiroolu nilẹ wa ti wọn pe ni The Crude Oil Refinery Owners Association of Nigeria, (CORANS), ti kilọ fun ijọba apapọ pe ki wọn ṣọra ṣe lori fifun ẹgbẹ awọn alagbata epo bẹntiroolu nilẹ wa niwee aṣẹ lati maa lọọ gbe epo wa lati ilẹ okeere nitori ewu to wa nibẹ fun ọrọ-aje wa.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ ọhun, Alukoro ẹgbẹ naa, Eche Idoko, ṣalaye pe o jẹ ohun to jọ ni loju pe awọn alagbata epo yii ṣi yari pe dandan, afi ki awọn maa lọọ gbe epo ti ko kun oju oṣuwọn wa lati Oke-Okun.
O ni ohun to ṣe ni laaanu lori ọrọ yii ni pe awọn oniṣowo epo kan kaakiri agbaye kan fẹẹ lo Naijiria bii ibi ti wọn yoo kan maa ko awọn epo ti ko kun oju oṣuwọn ti awọn orileede to wa ni Yuroopu kọ si wọn lọrun wa silẹ wa ni.
‘’Awa ko kọ ileeṣẹ to n ṣakoso ọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa ati iye ti wọn yoo maa ta a niṣẹ wọn o, awa kan n rọ wọn pe ki wọn ro o daadaa, ki wọn si jawọ ninu fifun awọn ti wọn lawọn fẹẹ maa lọọ ko epo ti wọn ti fọ wale lati Oke-Okun ọhun niwee aṣẹ, nigba ta a ni anito ati aniṣẹku epo bẹntiroolu nilẹ wa ta a le lo. Bi wọn ba tiẹ fẹẹ fun wọn paapaa, lasiko ti epo to wa nile ko ba too lo ni iru rẹ le waye, ki i ṣe pe ki ẹnikan kan ji lọjọ kan ko ni oun fẹẹ gba iwe lati lọọ maa gbe epo wa lati ilẹ okeere ki wọn le maa waa figagbaga pẹlu ẹnikan.
‘’Bi fifun awọn eeyan ni iwe aṣẹ lati maa lọọ gbe epo wa silẹ wa ba ti di iru-wa ogiri-wa, ipalara ni yoo mu ba ileeṣẹ ifọpo ti wọn ṣẹṣẹ n da silẹ kaakiri orileede yii. Awọn to n beere fun iwe aṣẹ yii ko ni ifẹ orileede yii lọkan, awọn kan fẹẹ sọ Naijiria di ibi ti wọn yoo maa gbe epo gbantuẹyọ ti ko kunju oṣuwọn wọle si ni. Ijọba gbọdọ da si ọrọ naa, ki wọn si daabo bo awọn ileeṣẹ epo to sẹṣẹ n fẹsẹ mulẹ kaakiri orileede yii.
‘’Ko sohun to ti daa ju ki a ni awọn ileefọpo to jẹ tiwa-n-tiwa nilẹ wa, niwọn igba ti ijọba ko lodi si ileefọpo didasilẹ nilẹ yii. Tijọba ba fẹẹ ran awọn ọmọ orileede yii ti wọn ko owo oogun oju wọn kalẹ lati da ileefọpo silẹ, wọn gbọdọ daabo bo wọn. Kaakiri ibi gbogbo lagbaaye nijọba ti maa n daabo bo awọn ileeṣẹ ti wọn ba da silẹ lorileede wọn. Ohun to yẹ ki wọn ṣe ni lati ṣatilẹyin fun awọn eeyan ti wọn ko owo wọn kale. Ohun to yẹ ki awọn eeyan maa sọrọ le lori bayii ni bi wọn yoo ṣe da ileefọpo silẹ kaakiri nilẹ wa, ki i ṣe ki wọn tun maa lọọ gbe epo wa lati ilẹ okeere’’.
O fi kun un pe awọn ọlọja epo lagbaaye n lo awọn ọlọja epo keekeeke lati ja ija orogun owo to n yọ wọn lẹnu nitori ojukokoro wọn lori ọrọ-aje Naijiria ti wọn fẹẹ maa taja si, ti wọn ko si ṣetan lati da si ọrọ aje Naijiria.
Eche ni, ‘’A ko sọ pe wọn ko le ta epo wọn ni Naijiria, ṣugbọn ohun ti a n sọ ni pe dipo ka maa kowo lọ sọdọ tiwọn lati maa ra epo ti ko kun oju oṣuwọn wa sile, kawọn naa kuku waa da ileeṣẹ ifọpo silẹ lọdọ wa nibi, ki i ṣe ki wọn waa sọ ilẹ wa di ibi ti wọn yoo kan maa rọ awọn epo ti ko kunju oṣuwọn wa. A o fẹ awọn ti yoo sọ ilẹ wa di ibi ti wọn yoo maa gbe ọja kọndẹ wa, ki wọn kuku waa da iṣẹ silẹ nilẹ wa lo daa, ki wọn le ran ọrọ-aje wa lọwọ lati mu un dagba.
‘’Wọn n sọ pe awọn n ta epo ẹdinwo ni ẹgbẹrun kan din diẹ (990), ọna wo ni epo ti ẹ n ta gba dinwo, nigba to jẹ pe awọn epo ti wọn kọ, ti wọn ni ko kun oju oṣuwọn ti wọn ko gba lọwọ yin lẹ wa n ta nibi ti ẹ n pe ni ẹdinwo. Ki i ṣe pe mo n gbe lẹyin ileefọpo Dangote o, nitori awọn ileefọpo mi-in wa nilẹ wa yatọ si ti Dangote.
‘’Nigba to ba fi maa di ọdun to n bọ, ileefọpo bẹntiroolu mẹta mi-in maa tun ti gbera sọ. Ki lo de ti a ko sọ fun awọn oniṣowo agbaye ti wọn fẹẹ maa ba nnkan jẹ fun wa yii lati kuku waa da ileeṣẹ ifọpo silẹ lọdọ wa. Ti a ba fopin si lilọọ gbe epo wa lati ilẹ okeere, anfaani nla ni yoo mu ba orileede wa’’.