Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Awọn ọdọ kan niluu Ado-Ekiti ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ekiti ti ṣewọde lati kede fun ijọba pe ki wọn fopin si ikọ to n gbogun ti idigunjale (SARS), eyi ti wọn gba pe o n pa awọn ọdọ nipakupa.
Lati aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, niwọde naa ti bẹrẹ, tawọn eeyan ọhun si lọ kaakiri ilu naa, koda wọn de ọdọ awọn ọlọpaa ati aafin Ewi tilu Ado-Ekiti.
Bi wọn ṣe n lọ ni wọn n pariwo ‘No more SARS’, eyi to tumọ si ‘A ko fẹ SARS mọ’, bẹẹ lawọn ọlọpaa tẹle wọn lati ri i daju pe ko si wahala tabi rogbodiyan kankan.
Awọn ọdọ naa ṣalaye pe ikọ SARS kan n lọ kaakiri lati gba owo lọwọ awọn ọdọ ni, bẹẹ ni wọn maa n tẹle ẹni ti wọn ba mu lọ sile lati gba nnkan-ini ẹ, eyi ti ko yatọ sigba tọlọpaa n jale.
Nigba to n ba wa sọrọ lori iwọde naa, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe ileeṣẹ naa ti ba awọn adari awọn ọdọ ọhun sọrọ, wọn si ti gba lati dawọ iwọde yii duro ki wọn le sọrọ nitubi-inubi.