Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Iwọde ifopin si SARS to n lọ kaakiri ipinlẹ lorilẹ-ede yii ko yọ ilu Abẹokuta silẹ, koda, kinni ọhun ti kan aarẹ, o kan agbaagba bayii, pẹlu bi agba ọjẹ onifuji nni, Alaaji Ṣẹfiu Alao, Bọlaji Amusan (Mista Latin) ati Ọdunlade Adekọla tawọn jẹ oṣere tiata ṣe da si i lọjọ Iṣẹgun, Tusidee,ọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.
Lati Panṣẹkẹ ni wọn ti gbera pẹlu ẹrọ gbohun-gbohun ti wọn fi n kede pe awọn ko fẹ SARS mọ, pe ki atunṣe si de ba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lapapọ, ki awọn to yẹ ko gbe ofin ro yee gbe ofin ṣanlẹ pẹlu bi wọn ṣe n pa araalu nipakupa, ti wọn tun n fiya jẹ alaiṣẹ.
Wọn wọde ọhun de Oke-Ilewo pẹlu ero rẹpẹtẹ lẹyin wọn, wọn si de Iwe-Iroyin ti i ṣe ọfiisi awọn akọroyin niluu Abẹokuta, nibi ti Mista Latin to jẹ Aarẹ TAMPAN ni Naijiria ti beere pe ki lo kan lẹyin bi ijọba ṣe fagi le SARS.
O ni ohun to kan ni ki wọn tun irori awọn ọlọpaa Naijiria ṣe, ki wọn fun wọn lowo-oṣu to dara, ki wọn yee jẹ kọlọpaa fowo ara ẹ ra yunifọọmu, ki wọn mu ayedẹrun fun wọn ni gbogbo ọna, kawọn agbofinro naa le yee fikanra wa ohun ti ko sọnu kiri lọwọ araalu.
Diẹ ninu awọn akọle ti wọn gbe dani lọjọ naa ni: ‘Ijọba apapọ gbọdọ fopin si ifiyajẹni tawọn ọlọpaa n ṣe’, ‘Mimura daadaa ki i ṣe ẹṣẹ’, ‘Iphone ki i ṣe ibọn’, ‘Ẹ ma pa mi nitori mo mura daadaa’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọdunlade naa fẹhonu ẹ han, bẹẹ ni Baba Oko, Ṣẹfiu Alao, naa ni afi ki atunto ba iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, bẹẹ naa si lawọn mi-in ti wọn tẹlẹ wọn wi.