Wahala yin pọ ju! Awọn kan to jẹ ti mo ba ti darukọ Bọla, tabi ti mo darukọ Bisi, ti wọn yoo bẹrẹ isọkusọ ni. Ọrọ ti wọn ko mọdi, wọn aa si maa da si i. Wọn le ni mo n sọrọ Bọla nitori ko fun mi lowo, n ko mọ ẹni to sọ fun wọn pe atọrọjẹ ni mi; tabi pe mo n wa ohun ti mo fẹẹ jẹ. Bi wọn ko si sọ iyẹn, wọn le ni mo fẹ ipo lọdọ ẹ, n ko mọ ipo to wa lọwọ ẹ ti mo fẹ, boya mo fẹẹ fi agbalagba ara bayii lọ sile aṣofin ni o, bi mo si fẹẹ di minisita ni, ko ye mi. Ko si ohun to kan mi ninu ọrọ oṣelu ilẹ yii ati ijọba wa ni Naijiria yii mọ ju bi aye iran Yoruba ko ṣe ni i bajẹ pata lọ. Nnkan wa ti bajẹ, ẹfun awọn Fulani n mu wa; ṣugbọn ọna ti ko fi ni i bajẹ ju bayii lọ naa ni a gbọdo maa tọ, ohun ti iran Yoruba ko fi ni i di ero ẹyin la gbọdọ mura si lati maa ṣe. Bi mo ba n ba Bọla tabi Bisi ja, ti mo si n sọrọ si wọn, ki i ṣe nitori nnkan mi-in, nitori ti wọn ko fẹran Yoruba ni.
Ọlọrun to awọn eeyan yii sipo nla, ipo ti wọn fi le ṣe Yoruba loore, ti Yoruba ko si ni i gbagbe wọn laye. Ṣugbọn awọn ko lo ipo naa fun wa, wọn n lo o fun ara wọn, ati fun awọn ti wọn ba le jokoo leṣẹ wọn lati maa bẹbẹ fun ipo kan tabi omi-in, ipo to si jẹ ti wọn ba debẹ tan naa, owo ilu ni gbogbo wọn fi n ko jẹ. Bẹẹ Bọla le ṣeto ijọba gidi fun ilẹ Yooba, o le lo agbara ẹ lati yi nnkan pada, Ọlọrun ko kan ran an bii alaaanu si wa ni. Ki lo de ti mo n sọ bẹẹ, ti mo si n tẹnu mọ ọn? Ohun to fa a ni pe Bọla ni agbara oṣelu ilẹ Yoruba wa lọwọ ẹ loni-in yii, bo ba si lo agbara oṣelu naa lati beere nnkan lọwọ awọn to n ṣejọba apapọ, tabi to lo o lati fi sọ fun wọn pe ohun ti Yoruba fẹ niyi, ki wọn ṣe e, awon eeyan naa yoo ṣe e. Nitori bi wọn o tiẹ bẹru oun funra ẹ, won aa bẹru pe Yoruba lo n ja fun, awọn Yoruba si pọ niye.
Ohun ti Bọla ri to fi n tẹle Fulani gọọ gọọ bayii ko ye emi gan-an ti mo n sọrọ yii, nitori ọlọgbọn eeyan ni mo mọ ọn si, ọpọ iwe itan lo si ti fidi ohun ti Fulani ti ṣe fun iran wa sẹyin mulẹ, ohun ti ko yẹ ki oun tun tori ẹ jin si ọfin wọn. Ṣugbọn gẹgẹ bi awọn tiṣaaju ti n ṣe, ti wọn maa ni awọn ti wọn jin si koto naa ko gbọn to ni, ko le ṣẹlẹ siru awọn, to si jẹ oju wọn bayii ni yoo ti ṣẹlẹ si wọn, iru ẹ loun naa gun le yii. Fulani maa n tan wọn lati jẹ ki wọn wa ohun ti ko sọnu kiri ni: ohun ti wọn yoo gbe le wọn lọwọ naa ni pe awọn aa fi wọn jẹ aarẹ. Bi Bọla ba ro pe oun le di aarẹ Naijiria ni 2023, tabi to ba ro pe Fulani le gbejọba foun, a jẹ pe aburo wa yii ko gbọn to bi a ti n ro pe o gbọn to. Fulani ti lo o, won si ti ju u sita, ko si ninu ile mọ rara, bi ko ba si ṣọra, to ba fẹẹ fi tipatipa wọle, won aa gbe nnkan mi-in le e lọwọ ni.
Yoruba n ja fun atunto, a n ja fun ijọba ẹlẹkunjẹkun ti yoo jẹ ijọba ti ipinlẹ ati ẹya wa nikan, a n ja fun ki awọn Fulani yee ji awọn eeyan wa gbe nilẹ baba wa, ki wọn maa fi wa ṣe ẹru, tabi gba ilẹ wa mọ wa lọwọ, nitori awọn Fulani yii ko sinmi o, gbogbo aburu ti wọn le ṣe fun wa ni wọn n ṣe. Ṣugbọn awọn Bọla wa niluu, won ko lọ sibi kan, wọn ko si le gbeja wa, kaka ki wọn si gbeja wa, wọn yoo dẹ awọn eeyan mi-in si wa lati da gbogbo ohun ti awa to ku ba n ṣe ru: Wọn aa fun wọn lowo, wọn aa fun wọn ni agbara ati ileeṣẹ iroyin ti wọn yoo ba sọrọ, awọn yii ni yoo ko ero jọ, ti wọn yoo tun gba ori redio ati tẹlifiṣan lọ, ti wọn aa ni ohun tawọn agbaagba Yoruba kan ni awọn n fẹ yii, ko sẹni to ran wọn, nitori agba Yoruba lawọn naa, awọn o si mọ itumọ ohun tawọn eeyan naa n ṣe.
Nigba ti a wadii ọrọ yii lọ ti a wadii ẹ bọ, wọn ni Bọla n sọ pe oun ko fẹẹ da si ọrọ Yoruba, bẹẹ ni Bisi naa n ti i lẹyin, pe agbara ijọba lawọn kọkọ n wa na, bi awọn ba gba agbara ijọba Naijiria tan, awọn aa mọ bi awọn ti ṣe le tọju Yoruba. Ọmọde to ni ti oun ba dagba, ori ẹyẹle loun yoo maa jẹ, ori ẹyẹle naa wa le jẹ ko dagba bayii bi! Awọn ti Bọla ro pe oun n tan yii, awọn ti gbọn ju u lọ, wọn mọ ohun to n wa, wọn si mọ pe awọn ko ni i fun un. Ni bii ọdun meje sẹyin, ọrọ kan yii naa ni Bọla sọ fawọn ọmọ Yoruba kan ti wọn wa lati Amẹrika lori ọrọ Yoruba, Bọla sọ fun wọn pe oun o le ja fun Yoruba nigba naa, agbara ijọba lawọn n wa, bi agbara ijọba ba bọ si ọwọ awọn ni 2015, gbogbo ohun ti Yoruba ba fẹ nigba naa loun yoo ṣe. Bisi naa wa nibẹ lọjọ yii ni ile Bọla, ti wọn jọ n da a, ti wọn n gbe e: Yoruba ko jẹ kinni kan loju wọn, bi wọn yoo ṣe gbajọba Naijiria ni 2015 lo wa lọkan wọn.
Ṣebi wọn si ti gbajọba naa, wọn ti gba a. O n lọ ọdun kẹfa bayii ti wọn ti n ṣejọba ọhun lọ, oore ki lawọn Bọla waa ri ṣe fun wa o, idagbasoke wo ni awọn Bọla mu ba wa lọdọ tiwa nibi to yatọ si ohun ti awọn to ku n jẹ anfaani rẹ o, afi ti wọn ba tiẹ tun rẹ wa jẹ si i lati fi tun tiwọn ṣe. Kin ni ko jẹ ki awọn Bọla le ṣe kinni kan fun Yoruba lati igba ti wọn ti gbajọba, wọn ṣaa ni agbara oṣelu lawọn n fẹ, ti ẹgbẹ awọn ba si ti gba agbara naa, igba naa lawọn too le ṣe kinni kan fun iran awọn. Wọn gba agbara naa, wọn si fi Buhari ṣe olori ijọba, ki waa ni anfaani oun ati awọn ti wọn gbe wa silẹ Yoruba, oore wo gan-an ni wọn ṣe wa. Ohun ti mo n mu jade ninu ọrọ yii ni awọn kan ti wọn jokoo sibi kan bayii ti wọn n sọ pe bi Bọla ti n ṣe yii lo daa, ọgbọn to fẹẹ da ni pe ko gbajọba lọwọ awọn Fulani, ohun to ṣe n ti wọn lẹyin niyẹn. Wọn ni bo ba ti le gbajọba lọwọ wọn, gbogbo ohun ti awọn Fulani gba lọwọ wa pata ni yoo da pada lọwọ kan.
Irọ gbuu! Bi a ko ba ṣe atunto si ofin ati eto ijọba Naijiria yii, tabi ki kaluku ṣe tiẹ lọtọ, bo ba jẹ bi ijọba yii ṣe wa naa lo wa, Bọla tabi ẹnikẹni lati Guusu Naijiria ko le ṣe ohun kan bi ijọba ba bọ si wọn lọwọ, koda ohun ti yoo ṣẹlẹ labẹ wọn yoo buru ju ti awọn Fulani funra wọn lọ. Ohun to maa jẹ ki eleyii ri bẹẹ ni pe ọpọ nnkan lawọn Fualani yii ti to kalẹ ninu ijọba Naijiria, ẹni yoowu to ba si wọle ijọba yii, ide ti wọn fi de e lẹsẹ wa nibẹ ti ko ni i jẹ ko le lọ sibikibi. Ide buruku meji lo wa, akọkọ ni eyi ti a n pe ni ofin Kótà (Quota System). Ẹkeji ni ofin Fedira (Federal Character). Ko si eyi to dara ninu ofin mejeeji yii, awọn ofin ti Fulani fi n ba ti Naijiria jẹ lati ibẹrẹ ni. Lara awọn ofin ti a fẹ ki Naijria yi pada ree; lara ofin atunto ti a n sọ yii, ko si bi ofin yii ṣe le wa ni Naijiria ti a oo bọ ninu oko ẹru awọn Fulani wọnyi, afi ba a ba pa ofin yii rẹ. Ofin yii naa ni o ni i jẹ ki Bọla ri kinni kan ṣe, koda ko di olori ijọba.
Ohun ti ofin yii wi ni pe bi ẹ ba fẹẹ gba eeyan si iṣẹ ijọba, tabi ti ẹ fẹẹ fi awọn eeyan ṣe minisita, darẹkitọ, tabi aṣofin, tabi ipo yoowu to ba ti ni i ṣe pẹlu apapọ ilẹ Naijiria, kota ni wọn aa fi pin in. Kota yii lo ṣe alaye pe ti ẹ ba fẹẹ gba ọgbọn eeyan sinu ṣọja, Hausa tabi Fulani yoo mu mẹẹẹdogun tabi ju bẹẹ lọ, eyi to ku ni Yoruba, Ibo ati awọn ara Naija Delta yoo pin, marun-un marun-un si ni tiwọn. Ohun to fa a niyi to jẹ ni ileeṣẹ ijọba apapọ kan, Hausa ni yoo yi ibẹ ka, titi dori awọn ti wọn wa ni ṣọja, awọn ti wọn n ṣiṣẹ ni Aṣo Rock, ati awọn ti wọn wa nileeṣẹ ologun gbogbo. Ofin yii naa ni wọn fi yan awọn eeyan si ile-igbimọ aṣofin, ti Hausa-Fulani fi ju idaji ẹya to ku lọ nibẹ. Bi Bọla ba waa gbajọba, to gbe ofin kan lọ si ile-igbimọ aṣofin, nitori ko le ṣe ohunkohun bi awọn aṣofin ko ba fọwọ si i, bi Hausa ko ba ti fẹ ofin naa, loju-ẹsẹ ni wọn yoo fi ibo wọn lu ofin ọhun pa. Nibo lo waa ti fẹẹ ri ibi ran Yoruba lọwọ o!
Ẹ maa ba mi bọ lọsẹ to n bọ.