Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ere asapajude lawọn eeyan agbegbe Orita Ọlaiya si Alekuwodo ati Old Garage, niluu Oṣogbo, sa laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba ti awọn tọọgi kan ya bo ibẹ pẹlu ada, aake ati igi lọwọ.
ALAROYE gbọ pe iwa ti awọn kan lara awọn to n ṣewode tako SARS yii hu lalẹ ana, Ọjọruu, Wẹsidee, lo fa a ti awọn kan fi jade lati tako wọn laaarọ yii.
Ṣe ni wọn ni awọn ọmọ ọhun bẹrẹ si i na awọn ọlọkada, wọn n na awọn ti wọn n kọja lọ, ti wọn si n da igboro ru.
Eleyii ni awọn tọọgi ọhun ro pe wọn tun le waa se laaarọ yii, ti awọn naa si dira ogun waa pade wọn.
Ṣugbọn awọn to n fẹhonu han nipa SARS ko jade rara titi digba ti a n koroyin yii jọ.
Erongba temi fun oride no wipe ki a pin, ki ile Yoruba dawa , ile igbo naa, benaa si ni Hausa , lai si yen, gege bi omó Yoruba tooto ti o ba do 2023 eje ki a fa igbakeji are orile ede Yi kaale olori orile ede yi gege bi ARE