Faith Adebọla
Ọkan ninu awọn ọmọ Pasitọ Adeboye to jẹ olori ijọ Ridiimu, Leke Adeboye, naa darapọ mọ awọn ọdọ to n fẹhonu han ta ko SARS ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niwaju ile ijọba to wa ni Alausa, Ikẹja.
Lasiko ti awọn ọdọ naa to jẹ Kristiẹni kora jọ pọ lati ṣe ijọsin ni ọmọ pasitọ naa darapọ mọ wọn ninu isin naa ti wọn pe ni ijọsin ti gbogbo ijọ Ọlọrun lati fẹhonu han, (Interdenominational protest Sunday Service) eyi ti wọn pe akori rẹ ni ‘Ogo igba ikẹyin’.
Ninu iwaasu to ṣe lọjọ naa lo ti sọ pe pẹlu awọn ohun to n ṣẹlẹ lẹnu ọjọ mẹta yii, isakoso ilẹ Naijiria ti n bọ si ọwọ awọn ọdọ niyẹn. O ni, ‘Mo fẹ ka mọ pe itumọ ohun to n ṣẹlẹ lasiko yii ni pe a ti n fa akoso orileede yii le wa lọwọ pẹlu bi a ṣe wa nibi ti a n ṣoju awọn mọlẹbi wa, ọrẹ wa ati orileede wa. Ibẹrẹ Naijiria tuntun la wa yii.
O waa gboṣuba fun awọn ọdọ naa pẹlu bi wọn ṣe pariwo sita lori inilara ati ijẹgaba to wa ni orileede yii, eyi ti wọn ti fun ni orukọ tuntun ti wọn n pe e bayii pe ‘sọrọ soke’.
O rọ wọn lati maa sọrọ lodi si ijẹgaba ati iwa inilara lorileede yii. Adeleke ni, ‘‘A jẹ iran ti ẹnikẹni ko le pa ohun mọ lẹnu. Awa ki i pa ẹrọ amohun-dun-gbamu, a maa n yin in soke ni.’’