Wọn ri agbari eeyan lori afara Post Office niluu Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Kayeefi lo ṣi n jẹ fawọn eeyan, paapaa awọn to ni ṣọọbu lagbegbe Post Office, niluu Ilọrin, nitori bi ajọ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, ṣe ri agbari eeyan lori afara to wa nibẹ laaarọ ọjọ Aje, Mnde, ọsẹ yii.

Agbari ọhun to jọ ti ọdọmọde ni awọn oṣiṣẹ NSCDC ri ninu lailọọnu dudu, ti wọn si tun gbe e ju sẹgbẹ titi lori afara ọhun.

Titi di bi a ti ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to mọ bi kinni ọhun ṣe debẹ, ṣugbọn awọn eeyan ni awọn to fẹẹ ṣoogun owo tabi to n ta ẹya ara eeyan lo maa gbe e ju sibẹ.

Ju gbogbo ẹ lọ, ileeṣẹ NSCDC ti n ṣewadi lori ẹ, igbagbọ si wa pe wọn yoo ṣawari awọn to huwa ọdaran naa laipẹ

About admin

Check Also

2023: Ẹgbẹ TOTT rọ Tinubu atawọn oludije yooku lati panu pọ gbe Ọṣinbajo kalẹ

Ọrẹoluwa Adedeji Ẹgbẹ kan, The Ọsinbajo Think Tank (TOTT), ti parọwa si aṣaaju ẹgbẹ oṣelu …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: