Aderohunmu Kazeem
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, o jọ pe awọn ọdọ ilẹ wa to n ṣewọde ta ko SARS yoo ba ijọba mu nnkan nilẹ pẹlu bi wọn ṣe sọ pe awọn ko ni i kuro nibi iwọde naa, bẹẹ ni awọn ko ni i da a duro rara.
Nibi iwọde naa to n lọ lọwọ ni Alausa ni wọn ti kede pe awọn ko ni i kuro ni ibi ti awọn wa naa. Wọn ni awọn maa wa nibẹ lati aago mẹrin irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ti isede naa ba ti bẹrẹ. Bẹẹ ni wọn rọ awọn ẹlẹgbẹ wọn pe ki wọn ma ba ọlọpaa ti wọn ba ri ja, ki wọn ma sọ wọn loko, ki wọn kan jokoo jẹẹjeẹ wọn.
Bakan naa ni awọn oluwọde yii to wa ni Lekki sọ pe awọn ko ni i lọ sile rara. Wọn ni ibi ti awọn duro si yii naa lawọn maa wa, ẹni ti ko ba si lọkan ninu awọn to wa nibẹ lati duro, ki wọn maa lọ sile, nitori o ṣee ṣe ki ounjẹ ma wa, o ṣee ṣe ki omi ma wa, ṣugbọn awọn maa ja ija naa debi to ni apẹẹrẹ nitori ẹtọ awọn ni labẹ ofin lati ṣe ifẹhonu han.
Wọn rọ awọn ẹgbẹ wọn pe bi awọn agbofinro naa ba ti de, niṣe ni ki wọn maa wo, ki wọn ma sọ ohunkohun. Bi wọn ba si mu ẹni kan, ki gbogbo awọn maa tẹlẹ wọn lọ. Awọn ọdọ yii sọ pe awọn ko ni ki awọn ọlọpaa ma ṣiṣẹ wọn, bi wọn ba ri awọn to n da igboro ru, ki wọn lọ sibẹ, ki wọn mu wọn, ṣugbọn ki wọn ma tori pe awọn kan n da ilu ru, ki wọn waa ni kawọn ma ṣe iwọde awọn.
Pẹlu bi ijọba ṣe paṣẹ, ti awọn ọdọ si ni aṣẹ naa ko ni i mulẹ, ko sẹni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo yọri si o.
Oodara awon ijoba gbo ohun ti awon odo nwi lowo yi lero