Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti pada tẹ Bọbọ, ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti orukọ rẹ gan-an jẹ Babatunde Idris, ọmo ọdun mọkandinlogun, to gun mẹkaniiki to n ṣiṣẹ ẹ jẹẹjẹ nigo n’Igbẹsa lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, ti ọkunrin naa, Salaudeen Lawal, si ṣe bẹẹ dagbere faye.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa yii, ni Salawu mẹkaniiki n tun mọto kan ṣe nibi ti wọn ti pe e pe ko waa ba wọn tun un ṣe. Mọto naa lo n ṣe lọwọ gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi, ti Bọbọ fi kọja, to si sọ pe mẹkaniiki naa ti fi ọkọ to n tunṣe di oju ọna. Ohun to dija naa ree, Idris fi mu akufọ igo, to fi gun Salawu lọwọ, bi iṣan ọwọ iyẹn ṣe ja niyẹn, lẹjẹ ba n ya.
Wọn sare gbe ọkunrin naa lọ sọsibitu to wa nitosi, ṣugbọn nibi to ti n gba itọju lọwọ lo ku si, oro iṣan to ja latari igo ti Bọbọ gun un lo si ran an sọrun.
Ọjọ Aiku ti Bọbọ gun mẹkaniiki naa pa lo ti sa lọ, ọjọ naa lawọn ọlọpaa si ti kede rẹ pe awọn n wa a o. Bi ẹnikẹni ba ba awọn ri ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn bẹru ẹ ni gbogbo Igbẹsa naa, ki wọn ta awọn lolobo.
Mọnde ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, lọwọ ba afurasi naa ni Surulere, niluu Eko, to sa lọ lẹyin to gun eeyan pa n’Igbẹsa.
Ọmọkunrin naa ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun loun huwa to fa iku Salawu, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi si fidi eleyii mulẹ.
Ẹka to n gbọ ejọ awọn apaayan ni wọn taari ọmọ ọdun mọkandilogun naa lọ gẹgẹ bii aṣẹ ti CP Edward Ajogun pa.