Ọlawale Ajao, Ibadan
O kere tan, eeyan mẹta lo ti gbemi-in mi nibi akọlu awọn ọlọpaa atawọn ọmọọta to waye niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.
ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn ọlọpaa ṣina ibọn fun awọn ọdọ ti wọn n ṣe iwọde SARS, eyi ni wọn lo bi awọn ọmọọta to wa nitosi ninu ti wọn fi kọju ija si wọn.
Ki awọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn tọọgi yii ti fibinu kọ lu teṣan ọlọpaa to wa ni Ọjọọ, niluu Ibadan, n ni wahala nla ba ṣẹlẹ.
Bii mẹfa ninu awọn to n ṣe iwọde yii lo fara pa yanna yanna, bẹẹ ni eeyan mẹta ku.