Gomina Eko ti fi ọjọ mẹta kun ofin konilegbele

Aderohunmu Kazeem

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti fi ọjọ kun ofin konilegbele to paṣẹ ẹ lana an.

Ni bayii, ọjọ mẹta ni ofin ọhun yoo fi wa kaakiri ipinlẹ Eko, ti ẹnikẹni ko si gbọdọ jade laarin ọjọ mẹtẹẹta yii, afi awọn ti wọn ba ni iṣẹ pataki ti wọn n ṣe fun ilu, to si pọn dandan fun wọn lati wa nita.

Bẹẹ lo bu ẹnu atẹ lu wahala buruku to bẹ silẹ ni agbegbe Lẹkki lana-an nibi tawọn ṣoja ti kọ lu awọn to n ṣewọde, ti wọn si gbẹmi wọn, tawọn mi-in paapaa farapa yannayanna.

Ṣa o, inu awọn kan ko dun nigba to sọ pe oun kede ofin ọhun lati fi ṣatilẹyin fun awọn to n wọde ta ko ẹṣọ agbofinro SARS.

 

Leave a Reply