Aderohunmu Kazeem
Awọn ọdọ ti wọn n fẹhonu han kiri Eko tun ti kọ lu ọfiisi awọn SARS to wa ni agbegbe Cement, lojuna Iyana-Ipaja si Osodi, l’Ekoo.
Bi wọn ti ya wọ ọfiisi ọhun ni wọn n ko awọn dukia ti wọn ba nibẹ jade, ti wọn si dana sun un.
Bi wọn ṣe n sun aṣọ awọn ọlọpaa ọhun lọwọ, bẹẹ lọkan ninu awọn ọdọ to n binu kiri yii mu ori orule ọfiisi naa gun, to si bẹrẹ si i ja a.