Faith Adebọla, Eko
Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ bayii ni pe wọn ti kọ lu ileeṣẹ iwe iroyin The Nation, l‘Ekoo, nitori ti wọn ni Bọla Tinubu lo ni in.
Kaakiri awọn ibi ti ileeṣẹ Bọla Tinubu, aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, yii wa ni awọn ọdọ ti inu n bi ti n lọ kaakiri lati alẹ ana, ti wọn si n ba ibẹ jẹ. Ni owurọ kutu oni yii ni wọn kọlu TVC, ileeṣẹ tẹlifiṣan ẹ to wa ni Ketu, l’Ekoo, bẹẹ ni wọn tun ti ṣemi-in bayii.
Ni bayii, adugbo kan to n jẹ Fatai Atẹrẹ, ni Muṣin, ni wọn tun gbe ija wọn lọ bayii, bi wọn si ti dọhun ni wọn tina bọ ileeṣẹ Vintage Press to n tẹ iwe iroyin The Nation.