Aarẹ ilẹ wa nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti tun kọ lẹta mi-in, si gbogbo ọmọ Naijiria, ati paapaa julọ si Aarẹ Muhammadu Buhari, lori wahala to bẹ ni ọpọlọpọ ipinlẹ ni Naijiria, to si ko hilahilo ba gbogbo eeyan pata. Ninu lẹta rẹ, Ọbasanjọ sọ bayii pe:
“Pẹlu ọkan wuwo ati aile-pe-ohun-to-n-ṣẹlẹ-yii-ko-kan-mi ni mo fi n kọwe yii si gbogbo ọmọ Naiijiria ati awọn ti wọn n ṣejọba, nipa rogbodiyan to n lọ jakejado orilẹ-ede wa bayii. Mo bẹ awọn ọdọ ilẹ wa ki wọn kọyin si ijangbọn fifa, ki wọn jokoo alaafia pẹlu awọn ti wọn n ṣejọba, ki wọn le jọ fopin si idarudapọ to ba gbogbo ilu yii.
“Mo fi asiko yii kọwe yii si Aarẹ Muhammadu Buahri funra ẹ, gẹgẹ bii olori ijọba ati olori ọmọ ogun lapapọ, ati gẹgẹ bii obi awọn ọdọ ti wọn jẹ ẹlẹgbẹ awọn ti wọn n ṣewọde pe awọn ko fẹ ọlọpaa SARS mọ yii, ati pe awọn n fẹ igbe aye daadaa funra awọn, pe ko lo ipo rẹ gẹgẹ bii olori lati da awọn ologun ati awọn agbofinro to ku duro, pe ki wọn ma kọju ija si awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde.
“Lati doju ibọn kọ awọn ti wọn n ṣewọde wọọrọ lai mubọn tabi ohun ija kankan dani ki i jẹ ki ọrọ niyanju, o maa tubọ n ba nnkan jẹ si i ni. Iwa ipaayan bẹẹ yoo mu ibinu awọn araalu ru soke, wọn yoo si koriira ijọba to ba ṣe bẹẹ si wọn, ko si ni i si aaye lati pari ija naa kiakia.
“O daju pe Aarẹ Buhari ati awọn eeyan rẹ ko ti i tọ gbogbo ọna alaafia to yẹ ki wọn tọ ko too di pe wọn ni ki awọn ṣọja lọọ doju ibọn kọ awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde yii. Eyi to tiẹ buru ni pe wọn tun n purọ pe awọn ko ṣe bẹẹ, nigba ti aworan ati fidio fihan daadaa si gbogbo aye pe ohun ti awọn ṣọja yii ṣe niyẹn. Ohun ti ko dara ti ṣẹlẹ na o, ṣugbọn gbogbo ẹ lo ṣee yanju bi Aarẹ ati ijọba rẹ ba tete mura lati pana to n jo naa, ko too di pe yoo burẹkẹ ju bayii lọ.”
Bayii ni Oluṣẹgun Ọbasanjo sọ, aarẹ Naijiria nigba kan.
Odara bee
Imoran toda ni babawa olusegun obasanjo gba aare wa ajagun feyiti muhamadu buhari kan je ki alafia joba larin ijoba ati awon odo oriledewa fa
Oro ni fun olori to ba setan lati gbo,ki Olorun gba Isa ko so