Awọn janduku ya wọ ọgba ẹwọn Okitipupa, wọn tun ọgọta silẹ ninu wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan bii ọgọta ni awọn ọdọ to jẹ ọmọọta ti tu sile lọgba ẹwọn kan to wa ni Okitipupa, ni olu ilu ijọba ipinlẹ Okitipupa nipinlẹ Ondo.

Niṣe ni awọn ọdọ tinu n bi ọhun ya wọn ọgba ẹwọn naa ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pẹlu nnkan ija oloro loriṣiiriṣii.

Bi awọn ẹsọ ọgba ẹwọn yii ṣe ri wọn ni wọn fere ge e nitori bi wọn ṣe pọ to ati awọn ohun ija oloro ti wọn mu dani. Taara ni wọn gba ibi ti wọn ti awọn ẹlẹwọn mọ lọ, ti wọn ja ilẹkun ibẹ, wọn si tu awọn ẹlẹwọn kan silẹ pe ki wọn maa lọ sile wọn lalaafia.

Ọpọlọpọ mọto ni wọn dana sun, bẹẹ ni wọn ba oriṣiiriṣii nnkan jẹ nibẹ ki wọn too kuro nibe.

One thought on “Awọn janduku ya wọ ọgba ẹwọn Okitipupa, wọn tun ọgọta silẹ ninu wọn

Leave a Reply