Aderounmu Kazeem
Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan orilẹ-ede yii naa lo sọ pe o ṣe pataki ki Aarẹ Muhammadu Buhari ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ, ọkunrin naa ti sọrọ o, lara ohun to si sọ ni pe ijọba oun ko ni i gba rẹdẹrẹdẹ laaye mọ.
Buhari sọ ọ ninu ikede to ṣe lana-an pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ to n ṣewọde tabi gbiyanju iwa janduku kan laarin ilu, aye yoo nira fun tọhun.
Bi awọn eeyan kan ṣe n fọ ṣọọbu, ti wọn n dana sun teṣan ọlọpaa kiri, tawọn mi-in si n sọ pe ifẹhonu han gbọdọ tẹ siwaju ni, Aarẹ Buhari ni ijọba oun ṣetan lati ba iru awọn ẹni bẹe na an tan bi owo.
O ni loootọ loun gba pe awọn kan ṣewọde tako awọn ọlọpaa SARS, ti ijọba si ti wa ojutuu si ọrọ ọhun lọgan.
Buhari fi kun un pe bi igbesẹ lati tu ẹṣọ SARS ka ṣe tete waye yẹn lawọn kan ṣe n foju yẹpẹrẹ wo ijọba oun, ti wọn bẹrẹ si da ilu ru, ṣugbọn ti ijọba oun ko ni i faaye gba iru ẹ mọ bayii.
Aarẹ tun ni ohun to foju han bayii ni pe awọn janduku ọmọọta kan ti ja kinni ọhun gba mọ awọn to ni ohun rere lọkan lọwọ, ati pe gbogbo iwa a-n-jo-teṣan ọlọpaa nina, a-n-tu-ẹlẹwọn silẹ, ati bi awọn eeyan yii ṣe n ba dukia ijọba jẹ kiri loun ko ni i gba fun wọn mọ, bẹẹ ẹni tọwọ ba tẹ, yoo foju wina ofin ni.