Ko ti i si ijọba kan ni Naijiria yii to gbogun ti iṣẹ ati oṣi bii tiwa o – Buhari lo wi bẹẹ

Aarẹ Muhammadu Buhari kede lana-an yii lasiko to n ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ pe ko ti i si ijoba kan ni Naijiria yii to gbogun ti iṣẹ ati oṣi bii ijọba tawọn, nitori gbogbo ọna lawọn n wa lati diin iṣoro ati iya to n jẹ awọn ọmọ ilẹ yii ku, nipa pipese fun airina ati airilo wọn. Buhari ni eyi gan-an lo si jẹ ki ọrọ awọn ọdọ ti wọn n fa wahala yii dun oun, nitori eto ti awọn ṣe, tori wọn lawọn ṣe ṣe e.

Olori ijọba ilẹ wa naa ni awọn ti ṣeto debii pe miliọnu lọna ọgọrun-un eeyan lawọn yoo yọ kuro ninu iṣẹ laarin ọdun mẹwaa si asiko taa wa yii, ti ko ni i si oniṣẹẹ ninu wọn mọ. O ni awọn ti tun ya biliọnu Naira marundinlọgọrin mi-in sọtọ lati fi pese iṣẹ adaṣe fawọn ọdọ ilẹ wa funra wọn.

Buhari ni ki gbogbo eeyan ranti pe ijọba yii naa lo ṣeto ẹyawo oriṣiriṣi fawọn eeyan, nibi ti awọn ti ya awọn agbẹ, awọn iyalọja, ati awọn onileeṣẹ keekeekee lọwọ. O ni lati igba ti arun korona si ti bẹrẹ lawọn ti n wa gbogbo ọna lati fun awọn eeyan lowo ninu ile wọn, ti awọn fẹẹ ba awọn onileeṣẹ keekeekee sanwo oṣu mẹta, ti awọn si wa iṣẹ fun awọn ọdọ kan. Aarẹ ni pẹlu gbogbo eyi, bi yoo ba fi to saa diẹ sasiko yii, ko ni i si kinni kan to da bii oṣi tabi iṣẹ ni ilẹ wa.

 

Leave a Reply