Aderounmu Kazeem
Bi ogunlọgọ ọmọ orilẹ-ede yii ṣe n binu, ti wọn n faraya lori ọwọ ti Aarẹ Muhammed Buhari fi mu bi wọn ṣe pa awọn ọdọ Naijiria nipakupa ni Too-geeti Leki, l’Ekoo, Sultan Sokoto, Ọba Sa’ad Abubakar, ti kilọ fun Buhari ko ṣe pẹlẹpẹlẹlori ọrọ yii o.
O lo ṣe pataki ki Buhari fọgbọn ṣe wahala to delẹ yii, paapaa bi inu ṣe n bi awọn ọmọ Naijiria lasiko yii latara adanu nla to ṣe awọn eeyan lori bi ẹmi ati dukia ṣe ṣofo lẹyin ti awọn ṣoja kọlu awọn ọdọ ni Lẹki, tọrọ ọhun si di rogbodiyan nla.
Ọba Sokoto sọrọ yii ninu atẹjade kan ti akọwe ijọ Jama’atul Nasril Islam fi sita, Dokita Khalid Abubakar.
Ninu ẹ lo ti rọ awọn ọdọ to n ṣewọde yii lati pada sinu ile wọn ki alaafia le jọba laarin ilu. Bakan naa lo gba ijọba niyanju lati fọwọ ẹlẹmu mu un, paapaa bi ọrọ ọhun ti ṣe la ọpọ ẹmi lọ, tawọn ọdọ paapaa ko ṣetan lati fojuure wọ awọn ẹṣọ agbofinro.
Ọba Hausa yii ti waa ke si awọn ologun naa ki wọn ṣe pẹlẹpẹlẹ pẹlu ọwọ ti wọn fi mu ọrọ ọhun ko ma baa burẹkẹ ju bayii lọ.
“Ti ijọba Buhari ko ba fẹlẹ mu ọrọ to dele yii, idaamu ati wahala rẹpẹtẹ lo le ko ba orilẹ-ede yii, nitori naa, ẹ jẹ ka ṣọra ṣe” Ọba Sokoto lo sọ ọ.