Florence Babasola, Osogbo
Adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo, Onidaajọ Kudirat Akano ti sọ pe ki ọmọkunrin kan, Gideon Aycent, maa lọ lalaafia nitori ko jẹbi ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an.
Iṣẹ agbegilodo (loggers) la gbọ pe Gideon n ṣe ko too di pe o ko sinu wahala naa lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2015.
Ẹsun ti awọn ọlọpaa fi kan Gideon ni pe oun lo ba awọn ikọ adigunjale kan ge igi ti wọn lo lati fi da awọn arinrinajo lọna loju-ọna Iwo si Ikire.
Fun odidi ọdun mẹta akọkọ ti wọn fi n gbe Gideon lọ si kootu ni ko fi ni agbẹjọro kankan lati gbẹnusọ fun un, oun kan ṣoṣo to ṣaa n tẹnumọ ni pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Laipẹ yii ni agbẹjọro Ọdunayọ Henry gba lati ba a rojọ ni kootu, nigba ti wọn si de kootu lọsẹ to kọja ni Ọdunayọ sọ fun adajọ pe ẹsun ti wọn ka si Gideon lẹsẹ ko nitumọ rara.
Agbẹjọro yii ni lai si ẹri kankan to daju, bawo ni awọn ọlọpaa ṣe maa sọ pe Gideon lo ge igi tawọn adigunjale fi da ọna lai ṣe pe oun nikan ni agbegilodo lagbegbe yẹn.
O rọ kootu lati ma ṣe faaye silẹ fun ẹnikẹni lati fiya jẹ alaiṣẹ, ki wọn da Gideon silẹ, ko le maa gbe igbe aye alaafia pada.
Onidaajọ Akano ni ootọ pọnnbele ni agbẹjọro olujẹjọ sọ, nitori ahesọ lasan ni gbogbo ẹsun ti awọn agbofinro fi kan Gideon.
Nitori naa, Akano ni oun tu olujẹjọ silẹ lati maa lọ sile rẹ lalaafia.