Jide Alabi
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla ti kilọ fun gbogbo awọn ọlọkada ipinlẹ Ọṣun pe ki wọn lọọ forukọ ọkada wọn silẹ laarin ọsẹ meji, bi bẹẹ ko, ijọba yoo fofin de wọn.
Ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni gomina ṣe ikilọ naa nigba to n ṣepade pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ ọlọkada ipinlẹ naa. O ni ohun ibanujẹ ati ijọloju lo jẹ foun bi awọn ọlọkada ṣe fi ara wọn silẹ fawọn eeyan lati lo lasiko rogbodiyan to waye naa.
Ijọba sọ pe igbesẹ yii waye nitori ipaniyan, idaluru ati buba dukia araalu jẹ nipinlẹ naa. Bakan naa lo kede pe awọn ọlọkada ko gbọdọ kọja aago mẹjọ alẹ nita lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ wọn. O ni awọn yoo fofin de wọn bi wọn ba kọ lati tele aṣẹ ijọba.
Oyetọla ni ‘’Ohun ti a gbọ nipa eto aabo fi han pe awọn eeyan yin ni wọn lo lati da wahala silẹ, lati da ilu ru, eyi to fa wahala ati aisinmi kaakiri ipinlẹ yii.
‘‘Mo fẹẹ sọ fun yin pe awọn eeyan yin paapaa ni wọn ṣatilẹyin bi wọn ṣe kọ lu mi lasiko rogbodiyan naa. Leyii to jẹ pe nigba ti awọn mọto to tele mi tun n sa lọ, awọn eeyan yin lo tun gbe ọkada to n le wa, ti wọn si fẹẹ fi ọkada wọn di wa lọna lati kọja. A tun ri i gbọ pe ọpọ awọn eeyan yin lo lọwọ si ole jija, ipaniyan ati fifini ṣowo.’’
‘’Eyi la fi n sọ fun yin ki ẹ sọ fun awọn eeyan yin pe ki gbogbo ẹka kọọkan ẹgbẹ ọlọkada fi orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn silẹ, ki wọn fi orukọ ọkada wọn silẹ, ki wọn si fun wọn ni aṣọ idanimọ ti wọn yoo kọ orukọ adugbo ti onikaluku wọn ti wa si. Eyi ko gbọdọ ju ọsẹ meji si ọjọ ti a ṣe ipade yii. Eyi yoo fun wa ni anfaani lati da ojulowo mọ yatọ si ayederu. Mo si feẹ gba ẹyin adari yin nimọran pe ke ẹ kilọ fun awọn eeyan yin ki wọn yee jẹ ki awọn eeyan lo wọn fun iwa janduku tabi ipanle.
Ki won lonbawa koju awon Boko haramu