Aderohunmu Kazeem
“Imukumu ti pọ ju fun awọn ọdọ orilẹ-ede yii, ti ajọ to n ri si itaniji ati ilanilọyẹ ko ba si tete mura, igbo, siga, ọti lile atawọn oogun oloro mi-in tawọn ọdọ n fa yii le ba wọn laye jẹ, o si le ko ba wa ni Naijiria.”
Arabinrin Mojisola Alli-Macauley, lo ṣe bayii sọrọ nile-igbimọ aṣofin Eko nigba toun naa n sọrọ lori bi awọn janduku kan ṣe ba nnkan rẹpẹtẹ jẹ l’Ekoo lọsẹ to kọja nigba ti rogbodiyan iwọde ta ko SARS bẹ silẹ kaakiri Naijiria.
Obinrin oloṣelu yii fi kun un pe ni kete ti awọn ọdọ ba ti mu imukumu tabi fa ifakufa wọn tan, ori ẹrọ ayelujara ni wọn maa n lọ, awọn ohun ti wọn si maa n kọ sibẹ, ati ohun ti wọn maa n gbe jade ki i ba oju mu to.
O ni, “Fun idi eyi, ileeṣẹ to n ri si ilanilọye ati itaniji (National Orientation Agency), gbọdọ ṣiṣe wọn bii iṣẹ lasiko yii, ki awọn ọdọ Naijiria too ba nnkan jẹ patapata. Niṣe lẹru maa n ba mi gẹgẹ bii obi lati fun awọn ọmọ mi ni foonu alagbeeka nitori mi o mọ ohun ti wọn le ba pade ninu ẹ. Ohun tawọn ọdọ n gbe sori ayelujara buru pupọ.”
Mojisọla fi kun un pe ilu oyinbo loun naa ti kawe, oun si mọ daadaa pe ki i ṣe gbogbo awọn ọdọ ibẹ naa ni wọn niṣẹ lapa, ṣugbọn awọn tọhun ki i bọ sigboro maa huwa janduku tabi sọ ara wọn di alajangbila kiri igboro.
O ni, “Ọdọ to pari iwe ti ko ti i niṣẹ le wa iṣe kan kọ, ko si tibẹ di akọṣe-mọṣẹ gidi, o le jẹ telọ aranṣọ, bẹẹ lo le di awọn to n ṣe ọsọ sile lọna to yatọ, eyi ti yoo fun un lanfaani lati di eeyan gidi. Ainiṣẹ lọwọ kọ lo maa n sọ eeyan di janduku, kaluku ni ko gbiyanju lati tun ọmọluabi ẹ ṣẹ.”
Ọrọ to sọ yii ti da wahala rẹpẹtẹ silẹ. Ohun tawọn ọdọ n sọ bayii ni pe ohun to ba ni lọkan jẹ ni bi awọn oloṣelu kan ṣe n foju amugbo wo awọn ọdọ Naijria nitori ti wọn fẹhonu wọn han si ohun ti wọn ko fẹ.
Wọn ni iyatọ wa laarin igbe aye awọn ọdọ ilu oyinbo ti obinrin yii fi n we awọn to wa ni Naijiria, nitori pe awọn oloṣelu wọn nibẹ, ko ni i maa ko ṣọja kiri fi pa wọn danu, lọjọ ti wọn ba bọ sita lati fẹhonu han sohun ti wọn ko ba fẹ.