Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Ẹka to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Ogun (Ministry of Education, Science and Technology) ti ṣalaye lẹkun-un rẹrẹ nipa bijọba ipinlẹ yii ṣe ni kawọn akẹkọọ wọle pada sileewe. Wọn nipele-ipele ni asiko tawọn akẹkọọ yoo fi maa wa ni kilaasi, ki i ṣe alakapọ bo ṣe wa tẹlẹ ki Korona too de.
Atẹjade to ti ọdọ Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ yii, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, jade lọjọ Aje ọsẹ yii, ṣalaye pe asiko ọtọọtọ lawọn akẹkọọ yoo maa lọ sileewe, ko ma baa si pe wọn yoo pọ ju, ti itakete sira ẹni ko si ni i ṣee ṣe.
Atẹjade naa fi kun un pe ijọba ti fi kun asiko tawọn akẹkọọ to fẹẹ ṣedanwo oniwee mẹwaa yoo maa lo nileewe, aago mejila ọsan si aago mẹrin irọlẹ ni wọn yoo fi maa wa ni kilaasi bayii lati le gbaradi daadaa fun idanwo aṣekagba ọdun 2020/2021.
Fun awọn akekọọ alakọọbẹrẹ ni kilaasi kin-in-ni de ikẹta, ati ipele akọkọ nileewe girama, aago mẹjọ aarọ si mọkanla ni wọn yoo fi wa nileewe gẹgẹ bi alaye ẹka eto ẹkọ ipinlẹ Ogun ṣe sọ.
Awọn to wa niwee kẹrin ni pamari titi de ikẹfa pẹlu awọn to wa nipele akọkọ girama titi de iwe kẹjọ (4-6,SS1-2) yoo wa nileewe lati aago mejila ọsan titi di aago mẹta ọsan nileewe ijọba.
Ni ti awọn jẹle-o-sinmi, aago mẹjọ aarọ lawọn yoo maa lọ sileewe, wọn yoo si maa ṣiwọ laago mọ́kànlá lawọn ileewe ìjọba.
Ọjọgbọn Arigbabu waa rọ awọn alakooso ileewe pe ki wọn ri i daju pe wọn tẹle gbogbo ofin to de itankalẹ Korona, ki wọn ma ro pe arun naa ti lọ patapata.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii nijọba ipinlẹ Ogun kede pe kawọn ileewe, ile igbafẹ, sinima, ile ijọsin atawọn mi-in maa ṣilẹkun wọn pada, pẹlu ikilọ pe wọn ko gbọdọ tẹ ofin Korona loju.