Ọwọ Amọtẹkun tẹ awọn janduku to lọwọ ninu rogbodiyan iwọde SARS

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Awọn afurasi bii mẹfa lọwọ ikọ Amọtẹkun ẹka tipinlẹ Ondo ti tẹ fun ipa ti wọn ko ninu rogbodiyan to suyọ latari iwọde SARS to waye ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu alakooso ikọ naa nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, pe ọwọ tẹ awọn janduku ọhun kaakiri awọn agbegbe ti rogbodiyan ti waye.

Diẹ lara awọn tọwọ tẹ naa lo ni wọn lọwọ ninu biba nnkan ini ijọba ati tawọn araalu jẹ, nigba ti wọn ri awọn mi-in mu pẹlu ẹru ẹlẹru ti wọn ji ko.

Mẹrin ninu awọn afurasi ọhun, Fẹmi Ibine, Oyewọle Ọlalẹyẹ, Ọmọtubora Iyanuoluwa ati Ọlamiju Sunday lo ni wọn ti jẹwọ ipa ti ẹnikọọkan wọn ko lasiko rogbodiyan naa.

O ni awọn ẹru bii aṣọ pẹlu bata ọlọpaa, ibọn ati ọkada ti wọn ba ni ikawọ awọn tọwọ tẹ ọhun fidi rẹ mulẹ pe wọn lọwọ ninu awọn teṣan kan ti wọn dana sun.

Oloye Adelẹyẹ ni eto ti n lọ lọwọ lati fi awọn janduku ọhun ṣọwọ sọdọ awọn ọlọpaa fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Leave a Reply