Faith Adebọla, Eko
Alaga ijọba ibilẹ Ajeromi-Ifẹlodun to wa lagbegbe Ajegunlẹ, nipinlẹ Eko, Alaaji Fatai Adekunle Ayọọla, ti fofin de igbokegbodo ẹgbẹ onimọto National (NURTW), jake-jado gbogbo agbegbe ijọba ibilẹ naa, bakan naa lo ni kawọn ọlọkada ati kẹkẹ Marwa ṣi lọọ wabi jokoo si na.
Ninu atẹjade kan ti alaga naa buwọ lu funra rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lo ti kede pe latari bi wọn ṣe dana sun sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ajerọmi-Ifẹlodun lasiko ifẹhonu han ta ko SARS waye lọse to lọ lọhun-un, awọn ti gbe igbimọ oluwadii kan kalẹ lati tọpinpin ohun to ṣẹlẹ, ati awọn to lọwọ ninu ọṣẹ buruku naa.
Latari eyi, bẹrẹ lati Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu yii, titi di igba ti igbimọ naa yoo jabọ iwadii wọn, ko saaye fun lilọ bibọ ọkada ati kẹkẹ Marwa, ko si saaye jija tikẹẹti kan fawọn onimọto.
Atẹjade naa sọ siwaju pe awọn agbofinro ti wa nitosi lati fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni to ba tapa si ofin yii. Ati pe kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ati alaga ẹgbẹ onimọto nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya (MC Oluọmọ) ti gbọ nipa ọrọ yii pẹlu.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwaa to kọja yii lawọn janduku kan ṣakọlu si sẹkiteriati ijọba ibilẹ naa to wa ni Opopona Baalẹ, nigba ti ina yanpọnyanrin iwọde ta ko SARS n jo geregere lọwọ.
Ọpọ banki, ẹrọ ipọwo ATM, ṣọọbu itaja nla, teṣan ọlọpaa, mọto atawọn dukia mi-in lagbegbe naa fara kaaṣa pẹlu.