Stephen Ajagbe, Ilọrin
Lẹyin tile-ẹjọ to ga ju lọ l’Abuja ti da ẹjọ ti Olori ile-igbimọ aṣofin Kwara, Yakubu Danladi, pe ta ko aṣofin PDP, Ọnarebu Jimọh Agboọla, nu lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, aṣofin naa ti ni adari ile naa ko ni i fẹẹ tẹ ara rẹ lati ma mu aṣẹ ile-ẹjọ ṣẹ.
Agboọla to ba akọroyin wa sọrọ lori foonu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ireti wa pe ile-aṣofin naa yoo gbe igbesẹ to yẹ lati bura wọle foun laarin ọsẹ yii.
O ni bi wọn ba si kọ lati ṣe bẹẹ, awọn yoo tẹsiwaju ninu ẹjọ toun pe ta ko olori ile-igbimọ naa ati akọwe lori bi wọn ṣe kọ lati mu aṣẹ ile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun to kede pe oun ni ojulowo aṣofin Ilọrin South ṣẹ.
Ọnarebu Agboọla ni suuru toun atawọn alatilẹyin oun ti n ni lati ọdun to kọja lawọn ṣi maa ni titi tileegbimọ naa yoo fi ṣe ohun to ba tọ.
Ṣe latigba tile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun ti gbe idajọ kalẹ ni abẹngan ile naa pẹlu awọn aṣofin APC mẹrinlelogun to wa nibẹ ti ta ko idajọ naa, ile-ẹjọ to ga ju lọ ni wọn gbe ẹjọ lọ, ti wọn si rọ ile-ẹjọ lati kede pe Agboọla ko lẹtọọ sipo naa.
Ṣugbọn ile-ẹjọ to ga ju lọ ti loun ko laṣẹ ati agbara labẹ ofin lati gbọ ẹjọ naa, nitori pe ile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun ni gbogbo ẹhonu ibo pari si.
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara ti gboṣuba fun idajọ ile-ẹjọ naa, wọn ki Agboọla ku oriire ijawe olubori rẹ nile-ẹjọ to ga ju lọ.
Atẹjade kan latọwọ Alaga ẹgbẹ naa, Ọnarebu Kọla Shittu, ni idajọ naa ti fopin si bawọn kan to ri ara wọn gẹgẹ bii ẹni to ga ju ofin orilẹ-ede Naijiria ṣe n tẹ ofin loju mọlẹ, ti wọn si n huwa ko kan mi.