Florence Babasọla, Oṣogbo
Yusuf Jẹlili ati Olumide Alabi ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun ladajọ ile-ẹjọ giga ijọba apapọ kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa lọọ fi pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ, lori ẹsun pe wọn ṣoniduuro fun ayederu lọya to ti sa lọ bayii.
Ayederu agbẹjọro naa, Fọlọrunṣọ Ọlayanju, la gbọ pe o lu awọn eeyan ni jibiti owo to le ni miliọnu mejila naira (#12.2m).
Nigba ti wọn si fẹẹ gba beeli rẹ ni kootu ni Jẹlili ati Alabi duro fun un, ṣugbọn ṣe ni Fọlọrunṣọ sa lọ raurau latigba naa.
Agbefọba to n ṣe ẹjọ naa, Muyiwa Ogunlẹyẹ sọ fun kootu pe ko sibi ti awọn ko ti i wa Fọlọrunṣọ si, pabo ni gbogbo rẹ si n ja si.
Awọn oniduuro mejeeji ni wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Adajọ Peter Lifu paṣẹ pe ki wọn ko awọn mejeeji lọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kejila, oṣu kọkanla, ti igbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ wọn.