Peter Ajayi n lọ sẹwọn gbere, ọmọ ọdun mejila lo fipa ba lo pọ l’Ekiti

Jide Alabi

Ọkunrin kan, Peter Ajayi, ẹni ọdun mọkanlelọgọta, ni ijọba ipinlẹ Ekiti ti ṣe idojuti nla fun bayii nitori to fipa ba ọmọ ọdun mejila lo pọ, ti wọn si tun ti sọ ọ si ẹwọn gbere.

Ọkunrin yii ni yoo jẹ ẹni keje ti ijọba ipinlẹ naa yoo dojuti fun nita gbangba.

Wọn ni ki wọn too ran ọkunrin yii lẹwọn gbere ni wọn ti kọkọ ṣe oro fun un gẹgẹ bii igbesẹ tuntun ti ijọba Fayẹmi ṣẹṣẹ bẹrẹ bayii lati fi pinwọ ifipa-bani-lopọ nipinlẹ Ekiti.

ALAROYE, gbọ pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o fipa ba eeyan sun nipinlẹ ọhun, niṣe wọn yoo ya fọto ẹ gadagba si awọn ibi kan to jẹ ojutaye kaakiri ijọba ibilẹ iru ẹni bẹẹ pẹlu akọle pe, ‘afipa-bani-lopọ-kan ree.’

Bakan naa ni wọn yoo tun fi orukọ ọdaran ọhun si atẹ ileeṣẹ eto idajọ lori ẹrọ ayelujara, bẹẹ gẹgẹ ni yoo tun wa ninu akọsilẹ pe iru ẹni bẹẹ ko ni i lanfaani lati ri aanu gba lọwọ ijọba, ti gomina ba tiẹ fẹẹ tu ẹlẹwọn kan silẹ fun aforiji.

Peter Ajayi ti wọn sọ sẹwọn gbere yii, ọmọ ilu kan to n jẹ Itapa Ekiti ni, nijọba ibilẹ Ọyẹ. Wọn ni Ijero Ekiti lo n gbe, nijọba ibilẹ Ijero, nipinlẹ naa.

Ṣaaju akoko yii nijọba ti da irufẹ sẹria yii fun awọn eeyan mẹfa kan nipinlẹ Ekiti. ̀Ọdun 2019 gan-an nijọba Fayẹmi ṣofin ọhun lati fopin si bi awọn eeyan ṣe n fipa ba awọn eeyan lo pọ l’Ekiti.

Adajọ agba nipinlẹ naa, Ọgbẹni ̀Ọlawale Fapohunda, ti sọ pe igbesẹ ṣiṣe idojuti fawọn irufẹ ọdaran bẹẹ ṣe pataki lati fọ ipinlẹ Ekiti mọ lọwọ awọn afipa-bani-lopọ.

O ni igbesẹ yii yoo jẹ ki awọn eeyan jawọ ninu iru iwa bẹẹ, bakan naa ni yoo jẹ ijanu fawọn obi lati maa kọ ọmọ wọn daadaa, nitori itiju nla ni yoo jẹ fun gbogbo wọn, nigba ti ijọba ba gbe aworan ati orukọ iru ẹni bẹẹ sigboro.

Leave a Reply