Aderounmu Kazeem
Ọkan lara awọn agba ikepo-pamọsi ileeṣẹ Oando to wa ni Marine Beach. lagbegbe Ijọra, l’Ekoo ti gbina bayii.
Iṣẹlẹ ọhun n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bi a ti ṣe n ko iroyin yii jọ, bẹẹ gẹgẹ ni ileeṣẹ ijọba Eko to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ti wa nibẹ pẹlu awọn oṣiṣẹ panapana lati wa ojuutu si i.
Agbẹnusọ fun ileeṣe LASEMA, Nosa Okunbor, sọ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ti wa nibẹ, bẹẹ lawọn ti n wa ojuutu si bi awọn yoo ṣe pa ina ọhun, ti awọn yoo ko tanka epo to wa lagbegbe ọhun kuro.