Festus pa ọmọ ọdun mejila n’Ibadan, o sa wa sipinlẹ Ogun, lọwọ ọlọpaa ba to o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọkunrin ẹni ogun ọdun kan torukọ ẹ n jẹ Festus Simon, ẹni ti wọn ni apaayan ni niluu Ibadan, ti wọn lo pa ọmọkunrin ẹni ọdun mejila nibẹ, to si sa wa si Ṣimawa, nipinlẹ Ogun.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ naa to ALAROYE leti ṣalaye pe ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni Festus pa ọmọde alaiṣẹ naa, o si sa kuro nile rẹ to wa n’Iyana ṣọọṣi, Iwo Road, n’Ibadan, o sa wa si Ṣimawa, nipinlẹ Ogun.

Bo ti de silẹ yii lo ni iṣẹ loun n wa, bẹẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti kede rẹ pe awọn n wa a. Bo ti de ipinlẹ Ogun ni olobo ti ta wọn ni teṣan ọlọpaa Ṣotubọ, ni Sagamu. DPO Samuel Adefọlalu atawọn ikọ rẹ si dọdẹ afurasi naa, wọn ri i mu l’Ọjọruu, ọjọ kẹrin, oṣu kọkanla yii.

Bi wọn ti mu Festus lo ti bẹrẹ si i ṣe awọn alaye kan lori iku ọmọ ọdun mejila naa, eyi to n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn. Ṣe wọn ti kọkọ mu ẹnikan tẹlẹ ti wọn ni oun ati Festus ni wọn jọ pa ọmọ naa.

Mimu ti wọn mu Festus nipinlẹ Ogun yii lo jẹ ki kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ yii, Edward Ajogun kilọ fawọn ọdaran eeyan pe ipinlẹ Ogun ki i ṣe ibi ti wọn le fori pamọ si.

O ni bo ti wu ki wọn sa pamọ to nipinlẹ yii, ofin yoo wa wọn jade.

Wọn ti kan sawọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ pe ọwọ ti ba ọdaran ti wọn n wa, wọn si ti taari rẹ si wọn fun itẹsiwaju ẹjọ naa.

 

2 thoughts on “Festus pa ọmọ ọdun mejila n’Ibadan, o sa wa sipinlẹ Ogun, lọwọ ọlọpaa ba to o

Leave a Reply