Jide Alabi
Aarẹ tuntun tí wọn ṣẹṣẹ dibo yan ní ilẹ America tí sọ pe ohun idunnu nla lo jẹ bí awọn eeyan ilẹ America ṣe ni igbagbọ nla ninu oun ati igbakeji ẹ.
Aarẹ tí wọn ṣẹṣẹ dibo yan yìí, Joe Biden, sọ pe ohun iwuri lo jẹ bí wọn ti ṣe fí ibo wọn gbe oun ati igbakeji oun, Arabinrin Kamala Harris, wọle sipo ọhun.
Eyi ni ọrọ akọkọ to sọ ni kete ti ileeṣẹ CNN to fọn rere ẹ wi pe oun lo wọlé sipo Aarẹ America.
Ninu iwe to kọ ranṣẹ lati fi dupẹ lọwọ awọn eeyan America lo ti sọ pe, “Lẹẹkan si i, awọn eeyan America tun fihan wi pe loootọ ni wọn ni igbagbọ to rinlẹ lọkan wọn nipa ijọba dẹmokiresi.
“Ni bayii, asiko ti to lati gbagbe ọtẹ ati ibinu, ki a sì tẹ siwaju pẹlu iṣọkan gẹgẹ bí orilẹ ede, bẹẹ ni ko si ohun rere ti a ko ni i ṣe ti a ba wa niṣọkan. Aṣalẹ oni laago mẹjọ (bii aago kan oru ni Naijiria) ni máa bá gbogbo èèyàn ilẹ America sọrọ, ẹ ku oju lọna mi.”