Igbimọ oluwadii ẹsun SARS so ijokoo wọn rọ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ni bayii, igbimọ to n wadii ẹsun ta ko aṣemaṣe ẹka ọlọpaa SARS l’Ekoo ti kede pe awọn ṣi so ijokoo wọn rọ na, boya o le ṣee ṣe kawọn pada sẹnu iṣẹ iwadii awọn lẹyin ọsẹ kan.

Ikede yii waye latẹnu alaga igbimọ naa, Adajọ-fẹyinti Doris Okuwobi, lọsan-an ọjọ Abamẹta yii ya ọpọ eeyan lẹnu, paapaa awọn ti wọn ti n reti lati fara han niwaju igbimọ naa ki wọn le ṣalaye ẹdun ọkan wọn ta ko bi awọn ọlọpaa ẹka SARS tijọba ti fofin de bayii ṣe fiya jẹ wọn latẹyinwa.

Okuwobi ni igbesẹ naa ko ṣẹyin bawọn ọdọ to ṣoju fun awọn to ṣewọde ta ko SARS laipẹ yii ko ṣe le yọju sibi ijokoo naa lọjọ Abamẹta yii, latari bi wọn ṣe ni ijọba n gbero lati gbẹsẹ le awọn asunwọn akaunti wọn ni banki.

Alaga igbimọ naa ni ti ko ba ṣee ṣe fawọn ọdọ yii lati pesẹ si ijokoo, ko ni i ṣee ṣe fun igbimọ naa lati tẹ siwaju tori iye eeyan to yẹ ko wa nikalẹ ki igbẹjọ too bẹrẹ ko ni i pe lai si awọn ọdọ naa.

ALAROYE gbọ pe ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ lọsẹ to kọja pe ileefowopamọ apapọ ilẹ wa le gbẹsẹ le akaunti awọn to ṣagbatẹru iwọde ta ko SARS to waye naa fun oṣu mẹfa, titi ti iwadii ti ileefowopamọ naa lawọn fẹẹ ṣe yoo fi pari. Akaunti bii ogun ni wọn ni aṣẹ naa de.

Lara awọn ti aṣẹ ile-ẹjọ naa kan Racheal Oluwarinu Oduala, to jẹ ọkan lara igbimọ oluwadii naa. Awọn mi-in tọrọ naa kan ni Moṣọpẹfoluwa Ọdẹṣẹyẹ, Ṣẹgun Victor Babatunde, Mary Oshifowora, Victor Solomon, ileeṣẹ Gatefield Nigeria Limited, atawọn mi-in.

Ṣa, a gbọ pe Okuwobi ti fi ọjọ ijokoo mi-in si Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu yii, pẹlu ireti pe yoo ti ṣee ṣe fun aṣoju awọn ọdọ naa lati wa nikalẹ, ki igbẹjọ le tẹsiwaju bo ṣe yẹ.

Leave a Reply