Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ni ko si ootọ ninu ahesọ to n ja ran–in ran-in nilẹ pe wọn ti yọ orukọ oun kuro ninu awọn oludije ti yoo kopa ninu eto ibo abẹle ẹgbẹ APC to fẹẹ waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ n bọ yii.
Akeredolu sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ Oludamọran agba rẹ lori ẹto iroyin ati ipolongo, Ojo Oyewamide, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ to kọja.
Gomina juwe iroyin ti wọn n gbe kiri ọhun bii irọ patapata, o ni ṣe lawọn alatako oun kan fẹẹ lo ahesọ naa lati ṣi awọn alatilẹyin oun lọna, ki wọn si da irẹwẹsi sọkan wọn.
O rọ awọn alatilẹyin rẹ ki wọn fọkan balẹ nitori pe oun ni idaniloju pe oun loun maa jawe olubori ninu eto abẹle to n bọ naa.
Ni kete ti wọn ti pari eto ayẹwo ti wọn ṣe fawọn mejila to gba fọọmu idije laarin ọsẹ to kọja ni wọn ti n gbe e kiri pe awọn oluṣayẹwo ọhun ti fagi le orukọ ọkan lara awọn oludije naa.
Orukọ Dokita Oluṣẹgun Abraham lawọn eeyan kọkọ n da, ṣugbọn akọwe iroyin rẹ sare fi atẹjade sita pe irọ to jinna soootọ lọrọ ọhun, ati pe ahesọ lasan ni.
Lẹyin eyi ni iroyin tun gba ilu kan pe Gomina Akeredolu gan-an lajere ọrọ naa ṣi mọ lori latari ipa to ko lasiko eto idibo aarẹ ọdun 2019. Wọn ni wọn yọ orukọ gomina ọhun lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o ṣatilẹyin fawọn oludije kan ninu ẹgbẹ oṣelu AA, to si ṣe bẹẹ kẹyin sawọn to n dije labẹ asia ẹgbẹ APC lasiko ibo gbogbogboo lọdun to kọja.