Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Lọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2020, ti iku pa agbabọọlu Rẹmọ STARS nni, Kazeem Tiamiyu tawọn eeyan n pe ni Kaka, latọwọ awọn ọlọpaa SARS, ọpọlọpọ eeyan lo dun, paapaa ni Ṣagamu tọmọ naa ti wa, wọn si bẹrẹ si i fẹhohun han kiri.
Lara ifẹhonu han ti ko ṣee gbagbe ọhun ni eyi to waye lọjọ kẹta iku Kaka, iyẹn lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji naa. Nibi ti wọn ti n fẹhonu han sawọn ọlọpaa, tawọn iyẹn naa n yinbọn pada ni aṣita ibọn ti ba baale ile kan, David Amusan, ẹni to n bọ lati ibi iṣẹ rẹ jẹẹjẹ. Bi ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn to niyawo ati ọmọ meji nile naa ṣe faye silẹ lojiji niyẹn.
Gẹgẹ bi iyawo oloogbe, Ọdunayọ, ṣe ṣalaye fun ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, iyẹn lẹyin oṣu mẹsan-an ti ọkọ rẹ ti ku, o ni iṣẹ birikila lọkọ oun n ṣe, ibi iṣẹ lo si ti n bọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun 2020 yii. Bo ṣe bọ saarin awọn ti wọn n fẹhonu han nitori Kaka tawọn SARS pa niyẹn, lo ba di pe ibọn ba a, bẹẹ ibọn awọn ọlọpaa ni.
Obinrin naa fi kun un pe ọmọ Ilọra, nipinlẹ Ọyọ, lọkọ oun, ko niyaa, bẹẹ ni ko ni baba mọ, awọn aburo meji lo ni David ni lẹyin, ilu Ilọra naa si ni awọn mọlẹbi rẹ yooku wa, ko si ẹnikan toun ri fun iranlọwọ lati oṣu kẹsan-an sẹyin ti ọkọ oun ti ku.
‘‘Mi o tete mọ pe nnkan ti ṣe mi lọjọ ti ọkọ mi ku, ile ni mo wa ti iyawo ọrẹ ẹ waa ba mi to beere pe ọkọ mi nkọ, mo ni wọn ti lọ sibi iṣẹ. Igba to ya ni wọn jẹ ki n mọ pe wọn ti gbe e lọ si Ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ, ni Ṣagamu. Wọn o tete tọju ẹ lọsibitu yẹn, ilẹẹlẹ bayii ni wọn tẹ ẹ si, wọn ko ya si i, o dẹ ti padanu ẹjẹ pupọ gan-an. Boya ka ni wọn tete tọju ẹ ni, o le ma ku. ‘‘Oun lo n gbọ gbogbo bukaata ile, o n dẹ n tọju emi atawọn ọmọ wa daadaa (akọbi jẹ ọmọ ọdun meje, ikeji jẹ ọmọ ọdun marun-un).
‘‘Ọkọ mi ko fẹ ki n maa ṣiṣẹ tẹlẹ, emi ni mo ni mi o kan le maa sun ki n maa ji, nitori ẹ ni mo ṣẹ n ta atẹ niwaju ile wa. David ti yawo ra ilẹ, owo LAPO lo gba, ori ilẹ yẹn la sinku ẹ si. Ẹni to ra ilẹ lọwọ ẹ gan-an ṣi n beere balansi bayii, mi o ti i rowo yẹn fun un.
‘‘Emi naa yawo LAPO, mo fi n taja. A o ti i sanwo yẹn bayii, gbese ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan ati mẹwaa (110,000) lowo tọkọ mi ya ṣẹku lati san, emi naa ṣi n jẹ wọn lẹgbẹrun lọna aadọrin naira (70,000).
‘‘Mi o rowo taja mọ bayii, nitori emi nikan lo ku ti mo n gbọ jijẹ-mimu awọn ọmọ mi, mo tun n sanwo ileewe wọn, ko dẹrun fun mi rara. Emi naa o dẹ ni baba, iya nikan ni mo ni. Lanlọọdu ti ni ki n kuro nile ti emi atọkọ mi n gbe ki wahala yii too de, Disẹmba to n bọ yii lo ni ki n kẹru mi jade, ko dẹ sibi ti mo le lọ, mo n waṣẹ ti mo le ṣe, mi o ri i.
‘‘Ẹ jọọ, ẹ ṣaanu mi o. O dun mi bijọba ipinlẹ Ogun ṣe lawọn ko mọ pe ẹnikan ku lẹyin iku Kaka, aburo Kaka gan-an waa ki mi nigba to gbọ pe ọkọ mi ku. Ẹ ba mi bẹ ijọba ipinlẹ Ogun ki wọn ṣaanu mi, kawọn ọmọ Naijiria naa dide iranlọwọ fun mi. Mo le ṣiṣẹ ti wọn ba fun mi niṣẹ ṣe, to ba si jẹ wọn fẹẹ fowo ranṣẹ si mi ni, akanti mi ree:0235483775, Wema Bank, Ọdunayọ Amusan.’’