Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lati ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, ti wọn ti kede Joe Biden gẹgẹ bii aarẹ adiboyan fun orilẹ-ede Amẹrika ni abuku oloronbo ti n kan awọn pasitọ Naijiria ti wọn ni Donald Trump to wa nibẹ naa ni yoo maa ṣejọba lọ. Bawọn eeyan ti n pe wọn niranṣẹ Eṣu lori intanẹẹti ni wọn n pe wọn ni wolii eke.
Ṣe latigba ti ọrọ ibo naa ti fẹẹ bẹrẹ lawọn ṣọọṣi kan ti wọle adura fun Trump, awọn mi-in gbaawẹ paapaa, bẹẹ la ri awọn ti wọn gbe patako ipolongo ati aṣọ ikede dani nigboro Eko ati lawọn ibi kan nilẹ Ibo, ti wọn ni ẹni Ọlọrun da ni Donald Trump, ọmọ Isrẹẹli ni pẹlu, awọn yoo ṣatilẹyin fun un ti yoo fi wọle ni.
Boya ka ni ibi ipolongo lo mọ, boya ko ba ma ba abuku pupọ de fawọn pasitọ yii, ṣugbọn awọn mi-in ninu wọn ti wọn ni ẹmi ti fi han awọn, pe Trump ni yoo wọle ni wọn tẹ ju.
Ọkan ninu wọn ni Pasitọ David Elijah, ẹni ti ṣọọṣi rẹ n jẹ Glorious Mount of Possibility, ni Yaba, l’Ekoo. Fidio ti pasitọ yii ṣe niwaju awọn ọmọ ijọ rẹ, to si ju sori ayelujara lo tubọ fabuku kan an, nitori ohun to sọ ninu fidio naa ni pe Donald Trump ni yoo wọle, ohun ti ohun ri niyẹn.
Pasitọ David Elijah tun sọ pe bi Trump ba ṣe n wọle sipo aarẹ bayii ni oloṣelu pataki kan naa yoo tun ku l’Amẹrika. O ni oloṣelu naa yoo pa ara rẹ nitori Trump to wọle ni. Pasitọ David tun sọ pe kawọn ọmọ ijọ oun ti Trump lẹyin, Ọlọrun yoo ṣe tiwọn.
Pasitọ yii naa lo ni oun fẹẹ lọ sorilẹ-ede China lasiko ti korona ṣẹṣẹ de. O ni awọn ara China ko ni wolii lọdọ wọn ni, bi wọn ba ni ojiṣẹ Ọlọrun gidi ni, ko si bi koro yoo ṣe maa yọ wọn lẹnu.
O ni korona ti tan nilẹ, o ti dohun igbagbe pata. Ṣugbọn titi dasiko yii, Pasitọ David ko lọ si Ṣaina, bẹẹ ni koro ko ti i lọ.
Bẹẹ naa ni Pasitọ agba ijọ ‘Awaiting The Second Coming of Christ,’ Adewale Giwa, rọ awọn eeyan ijọ ẹ pe ki wọn ṣe ti Trump, o lawọn ti ko mọ bi wọn ṣe n gbogun ti Korona ni wọn n gbimọ-pọ ta ko Trump.
Ṣọọṣi the ‘Living Christ Mission Inc’ naa ko gbẹyin ninu awọn to polongo fun Trump, Onitsha ti wọn fi kalẹ si naa ni wọn ti gbe akọle dani, ti wọn n ni ọdun mẹrin tun ku ti ọkunrin naa yoo lo si i nile ijọba.
Aiwọle Trump lo ko abuku ba awọn ijọ yii atawọn pasitọ wọn,titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n bu wọn bii ẹni layin lori intanẹẹti. Wọn ni ohun ti wọn fẹẹ jẹ ni wọn n wa, wọn o ri i nnkan kan latọdọ Ọlọrun.