Jide Alabi
Ijọba apapọ orilẹ-ede yii ti tu igbimọ to n dari akoso Yunifasiti Eko, UNILAG, ka, bẹẹ lo paṣẹ pe ki Ọjọgbọn Oluwatoyin Ogundipẹ pada sipo olori ileewe naa, nitori ọna ti wọn gba yọ ọ ko tọna rara.
Wẹsidee, Ọjọruu, ọsẹ yii ni igbesẹ ọhun waye, nni Ogundipẹ ba bẹrẹ si i ba iṣẹ rẹ lọ.
Ijọba apapọ sọ pe oun gbe igbesẹ naa latara abajade iwadii igbimọ to ṣabẹwo si yunifasiti ọhun, to si fidi ẹ mulẹ pe ọna ti wọn gba gbaṣẹ lọwọ Ọjọgbọn yii ku diẹ kaato.
Ọgbẹni Ben-Bem Goong, agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n rí si eto ẹkọ, sọ pe igbimọ to ṣabẹwo ọhun ri i pe ṣe ni wọn yọ Ogundipẹ lọna ti ko tọ, ti wọn si fi Ọjọgbọn Ṣoyọmbọ rọpo ẹ lai tẹle ilana to yẹ.
Bakan naa ni igbimọ yii ke si ijọba apapọ ko ṣe agbekalẹ igbimọ ti yoo lọ sileewe ọhun lati ṣewadii ẹsun tí wọn fi kan Ogundipẹ atawọn yooku ẹ.
Ninu ọrọ ti igbimọ ti ijọba apapọ gbe kalẹ fi sita lo ti sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbimọ to ṣabẹwo si ileewe UNILAG ti fọwọ si abajade awọn ọmọ igbimọ ọhun, bẹẹ lo foju han pe wọn ko fun ọga ileewe UNILAG yii lanfaani lati sọ tẹnu ẹ, fun idi eyi, ki wọn da a pada sipo rẹ ko maa ba iṣẹ ẹ lọ.
Ni bayii, wọn ti tu igbimọ ti Dokita B. O. Babalakin jẹ alága ẹ ka, bakan naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe oun lero pe igbesẹ yii yoo da alaafia pada sinu ọgba ileewe ọhun.