Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ọkada to to bii aadọta lawọn ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti gbẹsẹ le lori ẹsun ṣiṣe aigbọran sofin ti Gomina Rotimi Akeredolu ṣẹṣẹ fi lelẹ lori akoko ti wọn gbọdọ maa fi ṣiṣẹ.
Alakooso ikọ Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, lo fidi ọrọ yii mulẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. O ni gbogbo ọkada tawọn ba ti ri to n gbe ero lẹyin aago mẹfa irọlẹ si mẹfa aarọ ọjọ keji lawọn n gba, ti awọn si n gbẹsẹ le wọn.
O ni oun ti kọkọ ṣe ipade pẹlu olori awọn ọlọkada naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti gbogbo wọn si ṣeleri lati ba awọn ọmọ abẹ wọn sọrọ pe ko ṣeni to tun gbọdọ ṣiṣẹ mọ laarin asiko tijọba ti fi ofin de wọn.
Bakan naa lo ni awọn tun fi ẹrọ gbohungbohun kede kaakiri ilu Akurẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, lati kilọ fawọn eeyan ọhun lori ijiya to wa fun ẹni tọwọ ba tẹ nibi to ti n fi ọkada ṣiṣẹ lẹyin aago mẹfa irọlẹ.
Ọkunrin yii ni o jẹ nnkan iyanu foun pe awọn ikọ Amọtẹkun le ri awọn ọlọkada bii aadọta mu lalẹ ọjọ kan ṣoṣo fun riru ofin tijọba paṣẹ rẹ naa.
Ọsẹ to kọja nijọba kede fifi ofin de awọn ọlọkada kaakiri ipinlẹ Ondo pe ko saaye fun wọn mọ lati gbero tabi ki wọn gun ọkada wọn jade laarin aago mẹfa irọlẹ si mẹfa aarọ ojoojumọ latari iwa ọdaran to gbode lẹyin iwọde SARS to kọja.