Faith Adebọla, Eko
Ẹkọ ko ṣoju mimu lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde yii, nibi ipade tijọba apapọ pe ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nilẹ wa, Nigeria Labour Congress, NLC, si, pẹlu bi ipade naa ṣe fori ṣanpọn, ti awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ si fibinu kuro nibi ipade naa l’Abuja.
Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ naa sọ pe iwa abosi ati aiṣootọ nijọba n ṣe lori ọrọ ẹkunwo epo bẹntiroolu ati ti ina ẹlẹntiriiki.
Wọn ni ki ijiroro kan tabi ajọsọ eyikeyii too le waye laarin awọn atijọba, afi ki ijọba kọkọ da owo-epo pada si iye to wa tẹlẹ na, aijẹ bẹẹ, ko si idi fawọn lati fidi le aga jiroro ohunkohun.
ALAROYE gbọ pe gbogbo isapa awọn ikọ tijọba apapọ ran wa lati parọwa sawọn aṣaaju ẹgbẹ yii pe ki wọn bomi suuru mu lo fori ṣanpọn.
Lara awọn to ṣoju funjọba apapọ nibi ipade naa ni Akọwe ijọba apapọ, Boss Mustapha, ati Minisita fọrọ awọn oṣiṣẹ ati iṣẹ, Dokita Chris Ngige.
Kọmureedi Quadri Ọlaleyẹ, Alaga akojọpọ awọn ẹgbẹ oniṣowo, Trade Union Congress, TUC, ati Kọmureedi Emma Ugbaja, Aarẹ ẹgbẹ NLC, Kọmureedi Joe Ajaero, ati Akọwe agba ẹgbẹ NLC ni wọn ṣoju fawọn oṣiṣẹ.
A gbọ pe ohun to tubọ fa a ti awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ naa fi binu jade ni bi Dokita Ngige ṣe sọ fun wọn pe oun ni minisita fọrọ awọn oṣiṣẹ, oun loun maa dari ipade naa, ki i ṣe awọn ni wọn maa sọ oun toun maa ṣe foun, afi kawọn aṣaaju oṣiṣẹ kọkọ gbọ tawọn na, lawọn aṣaaju naa ba lawọn ko ṣetan lati gbọ ohunkohun ju pe kijọba kọkọ da owo epo ati tina mọnamọna pada.
Kọmureedi Ugbaja sọ fawọn oniroyin lẹyin ti wọn jade kuro nibi ipade naa pe ọtọ ni ibi tawọn atijọba jọọ fadehun si lori ẹkunwo epo, iyalẹnu lo jẹ fawọn lati ri i pe ko tojọ ko toṣu tijọba tun fi la ẹkunwo mi-in mọ epo, nigba ti awuyewuye lori eyi ti wọn ṣe ṣaaju ko tiẹ ti i rọlẹ.
“Eyi lawa fọkan si pe ko jẹ nnkan akọkọ ta a maa sọrọ le lori nibi ipade yii, ṣugbọn niṣe lawọn aṣoju ijọba n fẹ ka tẹti si eto adinniraku (palietiifu) tawọn ni, awa o si fẹẹ gbọ nipa iru eto abamoda bẹẹ, ko soootọ kan ninu iyẹn. Ohun to yẹ kijọba fi ṣaaju ni wọn fi kẹyin, niṣe ni wọn n gbe ọmọlanke ṣaaju ẹṣin to maa wọ ọ.”
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu yii, nijọba tun sọ owo-epo bẹntiroolu di aadọsan-an naira fun lita kan, bẹẹ ko ti i ju oṣu kan lọ ti ẹkunwo kan ti waye ṣaaju. Eyi lo mu kọpọ eeyan bẹnu atẹ lu ẹkunwo naa.