Stephen Ajagbe, Ilorin
Afurasi mẹta; babalawo meji, Jamiu Agbomọla, Abiọdun Lekan ati birikila kan, Wasiu Kareem, ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ẹgbẹrun marun-un naira lawọn maa n ta ẹya ara eeyan, koda lati ọdun 2018 lawọn ti wa lẹnu okoowo naa.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, nileeṣẹ ọlọpaa wọ awọn mẹtẹẹta lọ sile-ẹjọ Magisreeti kan to wa niluu Ilọrin, adajọ si ti paṣẹ ki wọn ko wọn pamọ sọgba ẹwọn na.
Akọsilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Shaad AbdulGaniyu lo fi to agọ ọlọpaa to wa niluu Ganmọ, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, leti lọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun 2020, pe oun ri Lekan to gbe baagi kan jade ninu ile, oun si fura si ohun to gbe sinu ẹ.
Nigba tawọn ọlọpaa tu baagi ti Lekan gbe jade naa wo, wọn ba oogun atawọn eegun eeyan ninu ẹ.
Lasiko tawọn ọlọpaa beere lọwọ rẹ pe nibo lo ti ri ohun to n gbe kiri, o jẹwọ pe ọga oun, Agbọmọla, to n gbe l’Agọ-Ọja, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, lo ni awọn eegun eeyan naa.
ALAROYE gbọ pe lẹyin tọwọ tẹ Agbomọla, o ni loootọ loun ti mọ Lekan tipẹ, ati pe ọmọọṣẹ oun ni.
Gẹgẹ bi akọsilẹ ọlọpaa, awọn mẹtẹẹta jẹwọ pe awọn maa n ta eyikeyii ẹya ara eeyan fun ẹni to ba nilo rẹ.
Agbẹjọro ijọba, Sajẹnti Adewumi Johnson, rọ ile-ẹjọ lati ko awọn olujẹjọ naa sahaamọ nitori pe ẹsun ti wọn fi kan wọn ki i ṣe eyi ti wọn le gba beeli rẹ, nitori o ni nnkan i ṣe pẹlu ẹmi eeyan. O ni iwadii ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju.
Adajọ Abimbọla Abioye ni ile-ẹjọ oun ko laṣẹ ati agbara labẹ ofin lati gbọ ẹjọ naa.
Fun idi eyi, o paṣẹ ki wọn ko wọn lọ sọgba ẹwọn na, o si sun ẹjọ naa si ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun yii.